Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Oludasilẹ ile ẹkọ giga Fasiti Afẹ Babalọla to wa ni iluu Ado-Ekiti, Afẹ Babalọla ti rọ gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, lati maa ṣe fọwọ ba tabi ṣe atungbeyẹwo idajọ ti ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa da lori aawọ aala ilẹ laarin ilu Ọffa ati Ẹrinle, eyi to segbe lẹyin Ẹrinle. O ni gomina ko lagbara lati yi idajọ naa pada.
Ninu oṣu kejila, ọdun 2018, nile-ẹjọ gbe idajọ rẹ kalẹ lori aawọ aala ilẹ to n waye laarin ilu mejeeji ọhun, eyi to segbe lẹyin ilu Ẹrinle, ṣugbọn awọn ọmọ bibi ilu Ọffa ko fara mọ idajọ naa, eyi to mu ki aawọ naa ṣi maa tẹsiwaju titi di akoko yii.
Gomina Abdulrazak waa gbe awọn igbimọ kan kalẹ ti wọn yoo wa ojutuu si aawọ naa laarin awọn ilu mejeeji ọhun laipẹ yii, eyi lo mu ki Babalọla jade lati ta ko igbesẹ naa, to si ni ki gomina ma dabaa lati fọwọ kan idajọ ile-ẹjọ.
Nigba ti Babalọla n ba awọn aṣoju lati ilu Ẹrinle sọrọ lopin ọṣẹ to kọja yii, o ni lati ọdun 1971, ni awọn ti n ba ẹjọ naa bọ niwaju Onidaajọ Funsho Daramola, to si jẹ pe awọn eeyan ilu Ẹrinle to jẹ onibaara oun ni wọn n bori ninu eto ẹjọ naa, fun idi eyi Gomina Abdulrazak, ko ni agbara kankan lati yi ipinnu ile-ẹjọ pada rara.