Ajagun-fẹyinti Ọgagun ori-omi Ndubisi Kanu, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko ati Imo laye ijọba ologun, ti dagbere faye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn lo ti ṣe diẹ ti baba naa ti n ṣaarẹ, to si ti n gba itọju labẹle bo ti lẹ jẹ pe ko si aridaju aisan to n ṣe e.
Ọjọ mẹta sẹyin laisan naa legba kan si i, ti wọn si gbe e lọ sọsibitu kan ni Victoria Island, ibẹ lo dakẹ si laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee.
Ọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 1943, o si gboye jade nileewe ẹkọṣẹ ologun ti Sandhurst Military Institutu lorileede United Kingdom.
Pataki kan ni Admiral Kanu jẹ ninu igbimọ to dari ẹgbẹ NADECO, ẹgbẹ naa si ja fitafita lati ri i pe ijọba Ọgagun Sani Abacha gbejọba fun Oloye Mọshood Kaṣimawo Abiọla, ti wọn gbagbọ poun lo jawe olubori ninu eto idibo sipo aarẹ lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993.
Lọdun 1975, oun nikan ṣoṣo ni ẹya Ibo ti wọn yan sinu igbimọ iṣakoso ologun nigba iṣejọba Ọgagun Muhammed Muritala.
Ọdun 1976, labẹ ijọba Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni wọn yan an sipo gomina ipinlẹ Imo, wọn si tun yan an sipo gomina ipinlẹ Eko lọdun 1976 titi di oṣu keje, ọdun 1977.