Toye Ajagun, gbajumọ olorin Juju kọlu Wasiu Ayinde, o loun atawọn kan ni wọn sọ orin fuji didakuda

Aderounmu Kazeem
Pẹlu bi orin fuji ti ṣe da loni-in, gbajumọ olorin juju, Uncle Toye Ajagun, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Magbe Magbe, ti sọ pe Wasiu Ayinde atawọn olorin bii tiẹ ti wọn n kọ fuji ni wọn sọ orin ọhun di idakuda loni-in.
Lori eto “Iwe Iroyin Parrot lori redio” ti wọn ṣe ni Oluyọle FM, nIbadan, ti Alagba Yinka Agboọla si dari rẹ ni gbajumọ olorin juju yii ti sọrọ ọhun laipẹ yii.
O ni, “Loni-in, gbogbo awọn nnkan ti wọn ko fi bẹrẹ orin fuji pata lawọn Wasiu Ayinde ti ko wọnu ẹ. Bẹẹ lo sọ pe o ni bi Dokita Sikiru Ayinde Barrister ti ṣe bẹrẹ orin ọhun to fi di ohun ti gbogbo aye tẹwọ gba bayii. Ko si ohun to n jẹ gita ninu orin fuji tẹlẹ atawọn nnkan mi-in ti wọn ti jo mọ ọn, bẹẹ lo ti mu un yatọ si ogidi orin fuji gẹgẹ bii ẹni to da a silẹ ṣe n kọ ọ nigba naa lọhun-un.”
Ajagun sọ pe gbogbo ohun ti wọn n ko wọnu orin fuji yii jẹ ko yatọ patapata si bo ti ṣe wa nipilẹ, bẹẹ ki i ṣe pe o mu ohun ọtun ba a bikoṣe pe o din in ku ni ti a ba n sọ nipa bi Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ti ṣe gbe e kalẹ nigba yẹn lọhun-un.

Nigba to n sọ nípa ipò orin Juju loni in yii, Toye Ajagun fi da awọn eeyan loju pe ipo iwaju ni orin ọ̀hún ṣi wa, bẹẹ ni ifẹ tawọn eeyan ni si i ko dinku nigba kankan nitori ti orin naa ko sọ ipilẹ to ti ni lati ibẹrẹ nu.
Bakan naa lo fidi ẹ mulẹ wi pe ko si orin kan to le le e wọle, paapaa bi awọn eeyan ti ṣe n sọ pe orin fuji gan-an ni ko jẹ ki awọn eeyan fẹẹ maa gbọ orin juju mọ.
Ajagun sọ pe, “Wasiu Ayinde Marshall gan-an mọ pe ipo iwaju ni orin Juju wa ni Naijiria, oun naa si mọ daadaa pe orin naa ko ku rara, bẹẹ lo maa n bọwọ fawọn to mọ laṣaaju nidii orin yii. Mo ranti daadaa ninu rẹkọọdu kan to ṣe laipẹ yii ninu eyi to ti forin ṣapọnle mi, bẹẹ lo forin gbe oriyin fun King Sunny Ade, Idowu Animaṣhaun, Ebenezer Obey atawọn eeyan wa yooku”.
Ṣiwaju si i, ọkunrin olorin ọmọbibi ilu Ẹgba yii sọ pe orin oun yatọ pupọ, ohun ti oun si maa n forin kọ julọ ni bi alaafia yoo ṣe wa laarin awọn ẹlẹgbẹ oun atawọn ololufẹ oun ti wọn n gbọ orin naa.
Tẹ o ba gbagbe, lọdun 1976 ni ọkunrin yii gbe rẹkọọdu kan jade, eyi to sọ pe alaafia loun fi wa saarin awọn gbajumọ olorin nla meji kan, Admiral Dele Abiọdun ati Emperor Pick Peter ti wọn n ba ara won ja nigba naa.
Nigba to n sọ nipa bo ṣe di gbajumọ olorin Juju, Toye Ajagun sọ pe, “Idowu Animashaun to ti di Pasitọ niluu Ibadan bayii ko ṣai ni ipa nla to ko ninu bi mo ṣe di olorin loni-in. Gita to máa n gbe kọrun nigba yẹn lo wọ mi loju, bi mo ṣe lọọ ba a niyẹn ti mo sọ fun un wi pe o wu mi ki maa kọrin. Agbegbe kan ti wọn n pe ni Ogunmokun ni Muṣin, l’Ekoo, lo mu mi lọ, nibẹ ni wọn ti maa n ṣe igbaradi orin ti wọn ba fẹẹ kọ. Ibẹ yẹn naa ni mo ti bẹrẹ si lu ilu konga, ki oloju si too ṣẹ ẹ, wọn ti kọ mi lawọn oriṣiriiṣi nnkan ti emi naa fi di agba ọjẹ ninu olorin loni-in.”
O mu ẹnu ba ọrọ Yinka Ayefẹlẹ paapaa, o ni olorin kan to gbiyanju lati ni ipa rere ni, bẹẹ lo fidi ẹ mulẹ wi pe ọkan lara awọn ̀ọmọ to gba abẹ oun kọja to wulo fun oun titi di ọla ni Ayefẹlẹ n ṣe.
O ni,“Mo ranti daadaa nigba yẹn ti Yinka Ayefẹlẹ wa lọdọ mi, eeyan kan tẹẹrẹ bayii ni, niṣe lẹru maa n ba mi ti oun naa ba n ko awọn irinṣẹ nla nla ti a n lo. Mi o ki i fẹ ko sunmọ ibẹ rara. Mi o mọ pe o le pada waa sanra bayii, ju gbogbo ẹ lọ ọpẹ ni fun Ọlọrun ọba.”
Gbajumọ olorin yii ti sọ pe ohun kan to maa n ba oun lọkan jẹ ju ni ki oun pẹ de ode ere. O ni tiru ẹ ba tiẹ ṣẹlẹ, gbogbo ọna lawọn maa n gba lati fi ṣere fawọn to ba pe awọn lode lọna to yatọ lati le mu inu wọn dun daadaa.
O ni, “Ṣe ẹ mọ pe, oriṣiriiṣi nnkan lo le fa idiwọ, ninu ẹ ni mọto wa, o le bajẹ loju ọna, ti eyi ba si waye, o ti di dandan ki a ṣere yẹn fawọn to pe wa lọna ti wọn a fi gbadun wa daadaa.”
Bakan naa lo sọ pe ọdun 1976 jẹ ọdun kan ti oun ko ni i gbagbe laelae nitori ọdun yẹn loun kọrin ra mọto akọkọ.”
Lakootan, Toye Ajagun ke si awọn olorin atawọn ọdọ lati tẹpa mọṣẹ, ki wọn si yẹra fun afẹ-aye to le ko ba ọjọ ọla wọn. O tiẹ ṣeleri fawọn ololufẹẹ pe oun tun n gbe awo orin nla kan bọ laipẹ yii, ti wọn yoo gbadun gidigidi.

Leave a Reply