Gomina Fayẹmi ti kilọ fun gbogbo oloṣelu o

Aderounmu Kazeem

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti pe awọn oloṣelu ẹgbẹ ẹ lati lo iriri to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria bayii fi ṣeto akoso to dara siluu, kirufẹ rogbopdiyan to n ṣẹlẹ kaakiri bayii ma le waye mọ lọwọ iwaju.

Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ ẹ sọ laipẹ yii lo ti fidi ọrọ ọhun mulẹ wi pe asiko niyi fun gbogbo oloṣelu lati ronu wọn, ki wọn si ṣeto ti yoo mu ilu rọrun fun tẹru-tọmọ. O kilọ fun won pe oloṣẹlu ti ko ba ṣe ohun ti araalu n fẹ, yoo fọwo ara rẹ fa wahala gidi sọrun ara rẹ ni

O ni bi awọn eeyan ṣe fẹhonu wọn han yii, ti wọn n ṣewọde tako iwa ininilara ati iṣekupani tawọn ọdọ n ri lọwọ awọn ọlọpaa SARS yii, iṣini-loju lo yẹ ko jẹ fawọn oloṣelu pe awọn araalu ko fẹẹ fọwọ ẹrọ mu iṣejọba ti ko ba ṣeto to yẹ fun wọn mọ.

Fayẹmi sọ pe, “Mo faramọ iwọde tawọn ọdọ ṣe tako ajọ SARS, ohun to dara ni lati beere ẹtọ wọn ati lati kọ ohun ti wọn ko ba fẹ.  Ṣugbọn ẹkọ to wa nibẹ fawa oloṣelu ni pe ka fọgbọn ṣe e lati asiko yii lọ, ka si maa fawọn eeyan ilu ni eto iṣakoso to yẹ.”

Ninu  ọrọ e naa lo ti rọ awọn eeyan kaakiri ilẹ Yoruba lati ṣe suuru pẹlu ijọba ki wọn si yẹra fun gbogbo iwa idaluru, to le ko gbogbo aye si wahala.

Fayẹmi rọ awọn ọba alaye paapaa, ati awọn olori ẹsin, atawọn oloṣelu pẹlu awọn agbaagba laarin adugbo lati lo opin ọse yii fi ba awọn eeyan sọrọ, ki wahala idaluru yii le kasẹ nilẹ patapata.

Bẹẹ gẹgẹ lo ba awọn eeyan ti ajalu ṣelẹ si lasiko wahala ọhun kẹdun gidigidi, to si fi wọn lọkan balẹ pe ijọba yoo ṣeto iranwọ fawọn ti wọn padanu awọn eeyan wọn atawọn ti dukia wọn ṣofo pẹlu.

 

Leave a Reply