Gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ atawọn ọmọ rẹ meji fẹẹ dupo ọba ilu Lafiagi

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Shaaba Lafiagi, ọmọ rẹ meji, Mohammed Kawu ati ọmọ Ọba Haliru to ku mẹrin, atawọn miiran ni wọn ti n dupo lati jẹ ọba Lafiagi bayii.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, ni ọba ilu Lafiagi, Alaaji Saadu Kawu Haliru, jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun-un (86), lẹyin aisan agba ranpẹ to ṣe e, ti wọn si ti sinku rẹ ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja, eyi lo mu ki ọgọọrọ awọn ti wọn ro pe ipo naa tọ si awọn fi n tu jade lati dupo ọhun.

Orukọ awọn ọmọ Haliru to jade laye ti wọn n dupo ni: Lukman, Danjuma, Salman ati Mohammed. Awọn miiran to tun n dupo ọba ni: gomina tẹlẹ nipinlẹ Kwara, Sahaaba Lafiagi, Mohammed Manzuma, to n gbe l’Abuja, adari agba ile-ifowopamọ Skye tẹlẹ, Kudu, aburo ọba to waja, Sambo Umoru, Aliyu Manzuma, Abubakar Bello, Ishiaku Abubakar ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọpọ awọn lookọ, lookọ ninu oṣelu, oṣiṣẹ ijọba atawọn oniṣowo pataki ni wọn ko ara wọn jade lati jọba Lafiagi, gẹgẹ bii orukọ tawọn igbimọ afọbajẹ gbe jáde.

Ohun ti a gbọ ni pe gomina tẹlẹ ọhun, Sahaaba Lafiagi, lo ti n wa ipo ọba yii lati ọdun pipẹ, ṣugbọn ti ko bọ si i fun un.

Babalawo ti wọn ka ori oku mọ lọwọ ni: Emi o mọ pe o lodi sofin lati gbe ori oku – Sẹmiu

Leave a Reply