Gomina Kwara ṣedaro Ẹmir Lafiagi to ku

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti ba mọlẹbi, awọn eeyan ilu Lafiagi ati gbogbo Kwara lapapọ daro iku ọba ilu naa, Alaaji Saadu Kawu Haliru, to jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun-un(86).

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni gomina kẹdun pẹlu awọn eniyan ilu naa lori ipapoda ọba wọn. O juwe ọba ọhun gẹgẹ bii ẹni to ti fi ipa rere lelẹ nigba aye rẹ, nipa mimu alaafia jọba niluu, ti ẹku n ke bii eku, ti ẹyẹ n ke bii ẹyẹ, bakan naa ni ọmọ eeyan n fọun bii eeyan nigba to wa lori aleefa, to si mu isọkan ati idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba Lafiagi ati gbogbo agbegbe rẹ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fi sita, ni gomina ti darapọ mọ awọn eniyan Ariwa Kwara, Aarin Gbungbun, ati Guusu ipinlẹ Kwara, lati kẹdun iku Emir Lafiagi, Alhaji Saadu Kawu OFR. Ọba onipo kin-in-ni, to fi tọkan tara sin ilu, lai fi ẹlẹyamẹya ṣe, to si mu alaafia ati isọkan fẹṣẹ mulẹ. Bakan naa lo mu awọn aseyọri ti ko lẹgbẹ ati  idagbasoke ba ilu.

Abdulrasaq ba igbimọ lọbalọba ni Ariwa ipinlẹ Kwara kẹdun, awọn mọlẹbi oloogbe ati gbogbo eniyan ilu Lafiagi lapapọ.

Leave a Reply