Ni Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, tilẹkun mọri pẹlu Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladọja ati ẹni ti ireti wa pe yoo di Olubadan, Sẹnetọ Lekan Balogun, pẹlu ẹgbẹ Agba Ibadan, CCll.
Ipade naa la gbọ pe o ni i ṣe pẹlu ede aiyede to ti n waye lori yiyan Olubadan ilẹ Ibadan tuntun. O ṣee ṣe ki gomina si fọwọ si Olubadan tuntun naa bi wọn ba ri gbogbo ọrọ ọhun yanju gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ.