Hijaabu: Eyi ni bawọn Musulumi ṣe kọ lu wa -Rẹfurẹẹni Dada

 

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Ijọ Onitẹbọmi, Baptist, nipinlẹ Kwara, ti ni igbesẹ tijọba gbe lati kede fifọwọ si lilo ibori fawọn akẹkọọ-binrin lawọn ileewe to jẹ ti ajọ ọmọ lẹyin Kristi ta ko aṣẹ ile-ẹjọ, nitori pe ẹjọ ọhun ṣi wa nile-ẹjọ to ga ju lọ, ko si bojumu bijọba ṣe n paṣẹ lori ohun to ṣi wa nile-ẹjọ.

Aarẹ ẹka to n mojuto apejọpọ ijọ Onitẹbọmi nipinlẹ naa, Kwara Baptist Conference, Ẹni-Ọwọ Victor Dada, lo sọrọ ọhun lasiko to n bẹnu atẹ lu akọlu to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ileewe girama ati alakọọbẹrẹ Baptist to wa ni Ilọrin, nibi tawọn kan ti wọn fura si pe wọn jẹ Musulumi ti wo geeti ileewe naa lulẹ, ti wọn si gbiyanju lati jo ṣọọṣi to wa nibẹ.

Dada ni awọn ọga ileewe Kristẹni nipinlẹ Kwara ti gba aṣẹ nile-ẹjọ lati ta ko lilo hijaabu lawọn ileewe naa, wọn si ti gbe ẹjọ de ile-ẹjọ to ga ju lọ, sibẹ ijọba tun tẹsiwaju lati sọ pe oun ti fọwọ si lilo ibori.

Nigba to n ṣalaye bi akọlu naa ṣe ṣẹlẹ, Rẹfurẹẹni Dada ni, “Awọn Onigbagbọ pejọ si ṣọọsi First Baptist to wa ni Surulere, Ilọrin, fun ifẹhonu han alaafia. Bi wọn ṣe n lu ilu ni wọn fọn fere, ti wọn si n kọrin. Ṣadeede lawọn alakatakiti ẹsin Musulumi ya de, ti wọn si ya bo wa.

“Apa awọn ọlọpaa ko ka wọn mọ, agidi ni wọn fi ja gẹẹti ati patako ijuwe to wa niwaju ileewe naa lulẹ, bẹẹ ni wọn tun n ju okuta lu wa fun bii wakati kan.

“Awọn ọmọ ijọ to duro lati da wọn lọwọ kọ atawọn agbofinro to tun pada lọọ tun ara mu ni ko jẹ ki wọn le dana sun ṣọọṣi naa. Wọn ju epo bẹntiroolu lu geeti ṣọọsi lati le dana sun un, wọn tun ba gbọngan nla to wa ninu ọgba naa jẹ.”

O ni lẹyin rogbodiya naa, eeyan mẹta lo dero ilewosan, awọn pasitọ wa lara awọn to fara pa.

O ṣalaye pe ṣe ni awọn eeyan ọhun halẹ pe awọn maa jo ileejọsin First Baptist naa lulẹ, bawọn ko ba ri i ṣe lojumọmọ, awọn maa jo o laarin oru.

O ni lẹyin ti wọn kuro nibẹ, wọn gba ileejọsin Apostolic to wa laduugbo Ẹruda, niluu Ilọrin, ti ko ni ileewe kankan tijọba n sakoso, lọ lati ba awọn nnkan jẹ nibẹ.

Ijọ Onitẹbọmi waa ni o jẹ ohun iyalẹnu pe ijọba to wa lode lonii ti sọ ọ di ti Musulumi, gbogbo ofin to ṣe fun anfaani awọn Musulumi ni, iṣesi ijọba gan-an bii ẹni gbe lẹyin ẹsin kan ni.

Dada ni, “Ohun to daju ni pe awọn ileewe wa ki i ṣe tijọba, ijọba kan jẹ alamojuto lasan ni. Lati ọdun 1974 tijọba apapọ ti gbe ilana ki ijọba maa mojuto awọn ileewe tawọn ṣọọṣi da silẹ kalẹ, ko sigba kan tijọba fọwọ si iru aṣọ kan fawọn akẹkọọ lati maa lo. Awọn ọga agba ileewe naa lo maa yan yunifọọmu kan laayo fawọn akẹkọọ. Awọn Kristẹni paapaa maa n tẹle gbogbo ofin to wa lawọn ileewe to jẹ ti Musulumi, wọn ki i gba ipejọpọ awọn ọmọlẹyin Kristi laaye nibẹ.

“Kawọn Musulumi ati ijọba ma ro pe didakẹ ta a dakẹ pe ẹru lo n ba wa o. Lati bii ọdun mẹẹẹdogun ṣẹyin, ijọba Kwara ko gba olukọ imọ bibẹli sawọn ileewe yii, to fi mọ tajọ ẹlẹsin Kristẹni, awọn olukọ to n kọ nipa ẹsin Musulumi ni wọn n gba lọpọ yanturu.

“Awa ko ni ifaaye gba hijaabu lawọn ileewe wa. A ṣetan lati duro ti igbagbọ ati ogun wa tawọn baba wa ninu igbagbọ ti fi lelẹ fun wa. Nitori naa, ki ijọba da awọn ileewe wa pada.”

 

Leave a Reply