Monisọla Saka
Ṣẹyin naa ṣi ranti ọkunrin ọmọ jayejaye ilẹ wa to n fi owo olowo se ara rindin, to maa n nawo bii ẹlẹda, to to si maa n patẹ rẹ sori ayelujara, to tun maa n wọ baaluu kiri bii ẹyẹ, Ramon Abass, ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppi, ti wọn mu niluu Dubai lọdun to lọ lọhun-un fẹsun lilu jibiti, ile-ẹjọ kan l’Amẹrika ti ran an lẹwọn ọdun mọkanla ati oṣu mẹta bayii o.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ da a lẹbi, wọn lo jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan an, kootu kan to n jẹ ‘The United States Central District Court’, to wa niluu California, lorileede naa, si ti sọ ọ sẹwọn ọdun mọkanla lori ẹsun jibiti ori ayelujara, lilo oniruuru ọna mi-in lati ṣe gbaju-ẹ fawọn eeyan ati ṣiṣe agbodegba owo (money laundering), ti wọn fi kan an.
Amọ ṣa o, ọdun mẹsan-an ati oṣu mẹta ni wọn lo ku fun ọkunrin naa lati lo lẹwọn gẹgẹ bo ṣe ti kọkọ lo ọdun meji latimọle lasiko ti wọn n ṣẹjọ ẹ lọwọ.
Ṣaaju akoko yii ni Hushpuppi ti n rawọ ẹbẹ si Adajọ Otis Wright ll, to n gbẹjọ rẹ lati ṣiju aanu wo o lori idajọ ti wọn ba fẹẹ ṣe fun un, ki wọn si ma fi ọpa wọn ẹwọn ọlọdun gbọọrọ foun nitori oun ko jẹbi ẹsun ipadi apo pọ pẹlu ẹnikẹni lati ji owo gbe, bẹẹ loun fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbefọba lori iwadii wọn ati paapaa ju lọ, nipa bi wọn ṣe n ṣiṣẹ ibi yii lori ẹrọ ayelujara, toun si jẹwọ fun wọn delẹdelẹ. Bakan naa lo tun ran ile-ẹjọ leti pe oun ṣe daadaa lasiko ti wọn n ṣagbeyẹwo awọn ninu iṣẹ imọtoto ayika toun ṣe lasiko toun wa ni ahamọ, oun si gba maaki to jọju fun iṣẹ imọtoto naa.
Tẹ o ba gbagbe, inu oṣu Kẹfa, ọdun 2020, lawọn ọlọpaa agbaye nawọ gan ọkunrin ẹni ogoji ọdun naa niluu Dubai, lorilẹ-ede United Arab Emirates (UAE), lẹyin ti wọn ti n tọpinpin ẹ fun ọjọ pipẹ lori ẹsun pe o ti lu ọgọọrọ awọn eeyan ni jibiti owo lati ori ẹrọ ayelujara lawọn orilẹ-ede bii Amẹrika, Qatar, UK atawọn mi-in lagbaaye.
Latigba ti wọn ko ti ri eegun to n jẹ Hushpuppi lori Instagram, nibi to ti maa n fẹla mọ yii, ni awọn ololufẹ ẹ to din diẹ ni miliọnu mẹta (2.8 million) ti wọn n tẹle e lori Instagram ti bẹrẹ si i dinku titi tawọn eeyan o fi ri oju opo ẹ mọ nibẹ, iyẹn nigba ti aọn alaṣẹ ikanni naa sọ oju opo rẹ kalẹ.
Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti wọn n ṣe iwadii ọmọkunrin yii ni ọrọ kan kọmiṣanna to n mojuto awọn iwa ọdaran to ba ṣẹ pataki ju lọ, Aba Kyari. Hushpuppi lo jẹwọ fawọn ọlọpaa naa pe ọkunrin ọlọpaa yii mọ nipa ọpọ jibiti tawọn n lu, bẹẹ lawọn maa n fun un lowo. Ọpọ igba ni wọn si ni ọlọpaa ti gbogbo eeyan fẹran daadaa nigba naa ko too ja bọ yii maa n ṣe agbodegba fun awọn.
Eyi lo jẹ ki awọn ara Amẹrika kọwe si ijọba Naijiria pe awọn n wa ọkunrin naa, ko waa foju kan awọn lori awọn ẹsun kan ti wọn fi kan an.
Ṣugbọn titi di ba a ṣe n sọ yii, Kyari ko ti i yọju sawọn ọlọpaa agbaye ti wọn n beere rẹ. Lasiko ti wọn n ṣe iwadii rẹ lọwọ ni wọn tun mu un pe o wa ninu awọn to n ṣe agbodegba fawọn to n ta oogun oloro nilẹ wa. Latigba naa ni ileeṣẹ to n gbogun ti lilo ati ṣiṣowo egboogi oloro (NDLEA), ti n ba a ṣẹjọ lori awọn iwa ti ko bofin mu to hu ọhun. Atimọle ọgba ẹwọn lo ṣi wa bayii pẹlu bi igbẹjọ rẹ ṣe n lọ lọwọ.
Ṣaa, Hushpuppi ti bẹrẹ irinajo ọlọdun mẹsan-an bayii ninu ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Amẹrika.