Iṣọ-oru ni mama yii dagbere ni Mowe, latigba naa ni wọn ko ti ri i mọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lati alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja ni awọn ọmọ ati ẹbi mama yii, Sarah Dosekun, ti ko si idaamu, ohun to fa a ko ju pe lati ọjọ naa ti mama ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin(67) naa ti dagbere iṣọ-oru ṣọọsi Sẹlẹ fun wọn ni ko ti pada wale, bẹẹ ni wọn ko ri i ni ṣọọṣi to loun n lọ.

  Ṣọọsi Sẹlẹ, Calvary Parish 1, to wa l’Ọgba, ni Mama Sarah Dosekun n lọ, ibẹ naa lo dagbere fawọn ọmọ rẹ lalẹ ọjọ naa, nitori isin iṣọ oru to fẹẹ lọọ ṣe. Mowe ni mama n gbe, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi ọmọ rẹ obinrin to n jẹ Janet ṣe wi, o ni ni nnkan bii aago meje alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni mama oun kuro nile, nigba ti aago mẹjọ ku iṣẹju mẹfa,  o ni mama pe oun lori foonu pe ibudokọ ‘Aṣeeṣe’ loun de bayii. Latigba naa lo ni oun ko ti ri mama oun ba sọrọ mọ, ti foonu rẹ ko wọle mọ.

Janet  fi kun un pe ẹgbọn oun to n duro de mama ni ṣọọṣi paapaa ko ri i ba sọrọ, bo ṣe n pe e ti wọn n sọ pe foonu ti ku lo n pe oun naa pe ki lo ṣẹlẹ, oun si n da a lohun pe oun naa ko ri wọn ba sọrọ o, bẹẹ wọn ti kuro nile lati aago meje kọja.

‘’Nigba ti a ko ri wọn titi di ọjọ keji la lọọ sọ fun wọn ni teṣan ọlọpaa  Mowe, a tun lọ si teṣan Warewa, pe boya wọn wa ninu awọn to lasidẹnti lori afara marosẹ Eko s’Ibadan lalẹ l’Ọjọbọ yẹn ni, ṣugbọn ko sohun to jọ bẹẹ. A o ti i gburoo wọn latigba yẹn, a o si rẹni kan pe wa pe wọn wa lọdọ awọn. Kawọn agbofinro ṣaanu wa la n bẹbẹ fun bayii o, nitori mi o gbadun ara mi latijọ ti mama mi ti sọnu’’ Bẹẹ ni Janet wi.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni kọmandi ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ, iwadii si ti n lọ ni pẹrẹwu.

Leave a Reply