‘’Iṣoro ipinlẹ Ọyọ kọja ohun ti Makinde le fọgbọn ori yanju’’

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi ọrọ aabo ṣe dẹnu kọlẹ nipinlẹ Ọyọ lẹnu lọọlọọ yii, awọn agbaagba ilẹ Ibadan ti bu ẹnu atẹ lu Gomina ipinlẹ yii, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ to fi n mu ọrọ naa.

Ninu ipade to waye laduugbo Ọja’ba, nigboro Ibadan, ni igbimọ Olubadan tilẹ Ibadan, gbogbo loyeloye, atawọn  Mọgaji gbogbo kaakiri ilu nla naa, ti fi aidunnu wọn han si bi Gomina Makinde ki i ṣee gbe igbesẹ akin nigbakuugba ti iṣẹlẹ to pe ipinlẹ Ọyọ nija lori ọrọ eto aabo ba waye.

Wọn ni ijọba adaṣe to n da ṣe laarin oun atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ẹ to yan sipo agbara lo fa a to fi jẹ pe ko si eto aabo to peye nibikibi ni ipinlẹ yii.

Awon agbaagba yii ṣalaye pe gbogbo bi awọn ṣe n gbiyanju lati da si ohun to n fa aibalẹ ọkan fawọn araalu lojoojumọ nipinlẹ Ọyọ lati le bori ipenija eto aabo ni Gomina Makinde ko kọbi ara si i rara.

Nitori ki ila ma baa waa ga ju onire lọ lawọn agbaagba ilu yii ṣe ke si Ọba Nureni Yusuf, Alajia ti Ajia, nijọba ibilẹ Ẹgbẹda, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti Gomina Makinde ti wa, pe ki wọn kilọ fun un, ko le mọ pe ọrọ ipinlẹ Ọyọ ki i ṣe nnkan tẹnikan le maa fọgbọn inu ara ẹ nikan yanju.

Lẹyin gbogbo abalọ-babọ apero yii ni ọkan lara awọn ikọ Olubadan, iyẹn Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun, rọ gomina lati tero ẹ pa pẹlu bo ṣe n fọwọ rọ igbiyanju wọn sẹyin.

Igbimọ awọn Mogaji ati gbogbo àgbààgbà ijoye n’Ibadan yii salaye siwaju pe ajọṣe lọrọ ipinlẹ Ọyọ, ki i ṣe nnkan tẹnikan le daya kọ. Awọn agbaagba ti wọn si ti mọ bọrọ ipinlẹ Oyo ti ri latilẹ naa ni wọn le fori kori pẹlu gomina lati wojutuu si i.

Leave a Reply