Ibanujẹ ti dori agba kodo fawọn mọlẹbi ọkunrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Uchenna, ni Abule Ọsun, lagbegbe Badagry, nipinlẹ Eko. Ibẹpẹ lọkunrin naa ni koun ka, nibi to ti fẹẹ ka a lo ti gan mọ ina ẹlẹntiriiki, lo ba ku patapata.
Irọlẹ ọjọ Satide opin ọsẹ to kọja yii, la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ. Wọn ni iṣẹ sikiọriti loloogbe naa n ṣe, awọn marun-un si ni wọn jọ n ṣiṣẹ.
Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) ṣalaye pe ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgọta naa ko dagbere fawọn to ku to fi gbọna ẹhinkule lọọ ka ibẹpẹ, o gbe akasọ kan dani ko le rọrun fun un, o si mu irin kan dani pẹlu.
Ọgbẹni kan, Jubril, ṣalaye pe ori akasọ yii loloogbe naa wa to ni koun fi irin ọwọ rẹ ka ibẹpẹ, ṣugbọn irin naa ṣeeṣi kan waya ina to gba ori ibẹpẹ naa kọja, bi ina ṣe gbe e niyẹn.
O ni ina to gbe e ọhun lo mu ko re bọ latori akasọ to wa, boya o fọrun ṣẹ ni o tabi bakan, ẹnikan o le sọ, ṣugbọn oju-ẹsẹ lo ku. O ti ṣe diẹ, ọjọ ti n bora, kawọn yooku ẹ too ṣakiyesi pe awọn o ri oloogbe naa, ni wọn ba bẹrẹ si i wa a kiri, ko si sẹni to ronu pe ẹni ti wọn n wa ti doloogbe.
Nnkan bii aago mẹwaa alẹ ni wọn lọọ kan oku ẹ nidii igi ibẹpẹ, wọn ri ọpa irin to fẹẹ fi ka ibẹpẹ ọhun ati akasọ to re bọ lori ẹ, akasọ ọhun ti ṣubu lu u mọlẹ sibẹ, ni wọn ba gbe oku rẹ lọ si mọṣuari oṣibitu Jẹnẹra Badagry.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun.