Ibo 1979 ku si dẹdẹ, n lawọn adigunjale ba ko girigiri ba awọn oloṣelu atijọba Ọbasanjọ (Ipari)

Ariwo, ‘yaa-fun-un yaa-fun-un’ motọ ọlọpaa lawọn eeyan to wa nile-ẹjọ giga n’Ikẹja kọkọ gbọ. Bi wọn ti gbọ ọ ni wọn dẹ eti wọn silẹ, bẹẹ lariwo fere ọlọpaa naa n sun mọ wọn si i. Oju lo n kan wọn! Ẹni ti a n gbeyawo bọ waa ba ni wọn, ko yẹ ki wọn maa garun rara, nitori ọdọ wọn kuku ni mọto awọn ọlọpaa naa n bọ, awọn lo si fẹẹ ja ẹru to n ko bọ gan-an fun. Ẹru wo lawọn ọlọpaa yii wa n ko bọ? Awọn adigunjale mẹfa ti wọn fẹẹ dajọ wọn nijọ naa ni. Awọn adigunjale mẹfa ti wọn fibọn ja ọgọrin ẹgbẹrun (N80,000) owo ileeṣẹ Boulos gba, ti wọn pa ọlọpaa meji, ti wọn si ṣe ọkan leṣe rẹkẹrẹkẹ ninu wọn. Kaluku ti gbọroyin pe ọjọ naa ni wọn fẹẹ dajọ wọn, ko si sẹni to fẹ ki kinni naa ṣeyin oun. Lọdọ igbimọ to n gbọ ẹjọ awọn adigunjale ni Ikẹja ni wọn yoo ti yanju ọrọ ọhun, Adajọ E. A. Hotonu si ni adajọ wọn.

Lẹẹkan naa ni ariwo ‘yaa-fun-un yaa-fun-un naa wọ inu ọgba ile-ẹjọ giga yii ni deede aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu karun-un, ọdun 1979. N lawọn ọlọpaa mẹrin ti wọn gun motosaikulu mẹrin ba kọkọ gun alupupu wọn naa wọle, ti wọn mura bii ẹni to n tẹle olori ijọba lọ sibi kan. Iyatọ to kan wa nibẹ ni pe ki i ṣe olori ijọba ni wọn n tẹle lọjọ yii, mọto Bulaaki-Maria (Black Maria), mọto ti wọn fi n ko awọn ọdaran kiri, ni wọn ṣaaju, bi awọn ọlọpaa alalupupu mẹrẹẹrin si ti wọle, bẹẹ ni mọto naa yọ lẹyin wọn, agbarigo ni, o dudu kirimu! Igba naa lawọn ọlọpaa, lọọya, oniroyin atawọn ero iworan bẹrẹ si i sare girigiri lọ sinu kootu ti wọn ti fẹẹ gbọ ẹjọ yii, wọn n wa ibujokoo to dara funra wọn. Oju awo lawo fi i gbọbẹ, wọn ko fẹ kẹnikan royin ohun to ba ṣẹlẹ nibẹ fun wọn, wọn fẹẹ foju ara wọn ri i.

Nigba naa, nita, mọto agbarigo naa ti rọ tikẹtikẹ, o si ti duro, n lawọn ọlọpaa ti wọn ti wa nitosi nibẹ ba yi i po. Awọn ọlọpaa lasan kọ lawọn eleyii, awọn ti oju wọn le koko ni, wọn wọ bata konko, wọn de fila irin sori wọn, ibọn to wa lọwọ wọn gun jalami, ko sẹnikan to jẹ sun mọ wọn. Ninu awọn ọlọpaa yii, awọn kan gbe kinni kan ti wọn n pe n maṣinni-gan-an-nu dani, wọn ni ibọn ti i fọ ile, ti i fọ ogiri ni, wọn lo le pa bii ogun si ọgbọn eeyan lẹẹkan, yoo kan maa rẹ wọn bii ẹni rẹla ni. Lẹyin ti awọn ọlọpaa naa ti duro kaakiri, ti wọn si mura ija bẹẹ ni wọn too silẹkun mọto agbarigo yii, nigba naa ni awọn ero inu rẹ bẹrẹ si i bọ silẹ nikọọkan. Ṣugbọn wahala igo lasan lọrọ awọn ọlọpaa ti wọn n fidi fọgba yii jọ loju awọn eeyan, nitori nigba ti awọn ti wọn n reti yii bọ silẹ, wọn ri i pe adiẹ ti kọọli ti gbe ni wọn, ko si ifun ninu wọn.

Bi wọn ti bọ silẹ lawọn eeyan ri wọn, wọn ko le rin daadaa rara, nitori niṣe ni wọn da bii alaaarẹ, wọn si ti ru hangogo, wọn waa n mi lẹgẹlẹgẹ. Yatọ si eyi, wọn ti de wọn ni ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ, wọn de wọn ni ṣẹkẹṣẹkẹ lẹsẹ, eyi to tumọ si pe bi agidi kan ba tilẹ wa ninu wọn, tabi ti ẹmi ija kan ba n gbe wọn ninu, ko si ọwọ tabi ẹsẹ ti wọn yoo fi ṣe’yẹn. Eeyan ko tilẹ le mọ pe itosi nibi, ni Adeniji Adele, ti wọn ti wọn mọle si, ni wọn ti n ko wọn bọ, eeyan yoo ro pe lati apa ọna ilẹ Hausa ni. Niṣe ni wọn fara balẹ gẹgẹ bii ọwọ onijangbọn ẹda ti i fara balẹ fun ankọọbu. Wọn ko le rin taara, niṣe ni wọn n kasẹ iyawo, nitori ọkọọkan ni wọn le gbe ẹsẹ, ẹni to ba gbiyanju lati gbe ẹsẹ ni meji meji yoo ṣubu ni. Bẹẹ ni wọn wọ turuturu dewaju adajọ, Adajọ Hotonu ati awọn eeyan rẹ. Bi wọn ti n wọle lawọn ero ti wọn wa nibẹ n wo wọn, ṣugbọn ko sẹni to le gbin, ohun gbogbo pa lọlọ ni.

Alaye ko pọ mọ, nigba ti awọn mẹfẹẹfa kuku ti rojọ tẹlẹ, ti olupẹjọ si ti fi idi ẹjọ tirẹ naa mulẹ, to jẹ ki wọn dajọ nikan lo ku fun wọn. Nelson Diefor ti i ṣe olori wọn duro, o dorikodo; Youperre Dakoru to jẹ atamatase wọn naa n wo baibai, okun ti mu aparo lẹsẹ poo. William Ogbolu to jẹ lebura mọ pe oun naa ti taja oun debi to lapẹẹrẹ, bẹẹ si ni Johnson Ibekwe to jẹ kuku ati iranṣẹ nileeṣe Boulos ti wọn ti ji wọn lowo yii mọ pe oun ti ṣe iṣẹ iranṣẹ daran, ko si jọ pe oun yoo tun ṣe iṣẹ iranṣẹ fẹnikan ni ileeṣẹ gidi kan ni Naijiria yii mọ. Ọlọpaa Mopol to wa laarin wọn, Lawrence Edemirukevu, lo n jẹka, abi kin ni ọlọpaa Moba n wa laarin awọn adigunjale, nigba to ni iṣẹ rẹ to n ṣe lọwọ. Oun naa dorikodo ni o, to n ṣẹju pako bii maalu rọbẹ, oun ati William Douglas, toun naa ni oniṣowo worobo loun, ọja pẹẹpẹẹpẹ lo n ta.

Olupẹjọ ijọba, Adekunle Ilọri, to fidi ẹjọ gbogbo mulẹ wa nibẹ nigba ti Adajọ Hotonu bẹrẹ idajọ rẹ, ohun to si kọkọ ṣe ni lati ṣalaye awọn eeyan meji kan ninu awọn adigunjale naa, o ni awọn gan-an leṣu beleke, awọn ni wọn wa nidii ohun gbogbo. Ẹni akọkọ ni Nelson Diefor, ẹni ti oun funra ẹ ti jẹwọ pe oun lolori wọn. Adajọ ni ọrọ rẹ dun oun gan-an, nitori ki i ṣe oun lo yẹ ki wọn ba ni iru ipo bẹẹ, bẹẹ ni ko gbọdọ jẹ oun ni wọn yoo ka awọn iwa buruku bẹẹ mọ lọwọ. Idi ni pe Katikiisi ni baba Nelson yii. Ni ipinlẹ Rivers, ni Kamabim, ni wọn ti bi i. O kawe nibẹ, o kawe nilẹ Ibo, l’Owerri, ko too waa maa kawe ni Onikẹẹ, Yabba, l’Ekoo. Iwe mẹsan-an lo kawe ẹ de to fi ni oun o ka mọ lọdun 1966, lo ba wọṣẹ nileeṣẹ Port Authority, bi ogun abẹle si ti fẹẹ bẹrẹ lo gba ṣọja lọ, wọn si jọ jagun abẹle ni, afi bo ṣe yi biri to waa pada di adigunjale.

Adajọ sọrọ Youpelle Dakoru naa, o ni ọdaju apaayan gan-an ni, oun ko si ri iru ẹni bẹẹ ri. O ni tirẹ naa buru nitori ọmọ ọlọpaa loun, ọga ọlọpaa ni baba rẹ, ohun to si jẹ ko jẹ ọgba awọn ọlọpaa ni Ọbalende, l’Ekoo, ni wọn bi i si niyẹn, bo tilẹ jẹ ni Yenagoa, nipinlẹ Rivers, lawọn naa ti wa. O kawe l’Ekoo, Ibadan lo si ti kawe mẹwaa jade ki ogun abẹle too de, toun naa si kọri si ṣọja. Oun naa ba wọn jagun abẹle, afi bo ṣe kuro loju ogun to n waa paayan kiri igboro lati gba owo ọwọ wọn. Ibinu eyi ni adajọ ko ṣe wo wọn loju, afi lẹẹkan naa to kọju si wọn, gbolohun kan naa lo si wi jade, o ni, ‘Wọn yoo yinbọn pa yin ni, afi ẹni kan ṣoṣo ninu yin ni yoo ṣẹwọn ọdun mẹẹẹdogun!’ Ọlọpaa moba yẹn nikan ni wọn ni yoo ṣẹwọn, idi si ni pe ko ba wọn lọ soko ole naa, wọn ni ọta ibọn lo fun wọn, ko si mọ ohun ti wọn fẹẹ fi i ṣe.

Bayii ni wọn dajọ iku awọn marun-un, ti wọn si ni ki wọn tete yinbọn pa gbogbo wọn. Aye ijọba ologun igba naa ko si ni sunmẹ-sunmẹ ninu, paapaapa ni wọn yoo ṣe gbogbo ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ọjọ kẹrin ti wọn dajọ iku yii naa ni wọn ti mu wọn lọọ pa, ọjọ Satide to tẹle e ni, ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun-un, ọdun 1979. Bawọn ero ṣe mọ pe wọn yoo pa wọn lọjọ naa ko yeeyan, nitori pitimu ni wọn pe seti okun. Koda, awọn eeyan wa lati awọn ipinlẹ mi-in ti wọn waa woran awọn adigunjale ti okiki wọn lalu ja. Bo tilẹ jẹ pe aago mẹsan-an aarọ ni wọn fi pipa wọn si, lati bii aago meje lawọn eeyan ti kunbẹ, ero ko si dakẹ titi ti wọn fi ko awọn ole naa de, ti wọn de wọn mọ agba, ti wọn si kẹyin wọn sokun. Lẹyin naa ni awọn ṣọja to lọwọọwọ, ti wọn feesi awọn adigunjale naa nikọọkan.

N lọga wọn ba peṣẹ fun wọn, ‘fayaaa!’ Bẹẹ ni ina ibọn dahun lọ ‘karakaka’, n lawọn adigunjale naa ba dorikodo, ọta ibọn fa wọn ya pẹrẹpẹrẹ. Bẹẹ lopin de sawọn adigunjale to ja ọgọrin ẹgbẹrun gba lẹẹkan, ko si tun si ẹjọ ole ti wọn ṣe lasiko naa, lati igba ti wọn ti ṣe ẹjọ Oyenusi, to tun la ariwo lọ ju ẹjọ awọn Dakoru yii lọ. Ọkan awọn ijọba Ọbasanjọ pada balẹ, awọn oloṣelu naa fi ẹdọ lori oronro, wọn si n ba kanmpeeni wọn lọ, wọn n wa oloṣelu ti yoo gbajọba lọwọ Ọbasanjọ nibẹrẹ oṣu kẹwaa, 1979.

Leave a Reply