Iroyin ti gbogbo ọmọ Naijiria ti n reti ni. Loootọ wọn ti gbọ oriṣiiriṣii iroyin lori ọrọ ẹjọ awọn adigunjale wọnyi, iyẹn awọn adigunjale ti wọn ja owo ileeṣẹ Boulos gba, ṣugbọn wọn ko mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ti gbọ ẹjọ naa lọtun-un losi, paapaa nigba ti wọn ko tun tete gbọ nnkan kan mọ. Ṣe wọn yoo da wọn lare ni, nitori awọn mi-in ta ku ninu wọn pe awọn ki i ṣe adigunjale, wọn ṣi awọn mu ni. Ṣe wọn yoo da wọn lẹbi ni, ti ọrọ wọn yoo si ja siku bo ti yẹ ko ja si. Gbogbo eyi lawọn araalu n ro, ti awọn oṣelu gbogbo naa n gbe kiri, nigba to ṣe pe ko si ẹni ti ọrọ ọhun ko ko laya soke. Awọn adigunjale ti wọn ko ọkan gbogbo eeyan ilu soke ni wọn, nitori ni 1979 yii, ko sẹni kan to mọ pe awọn adigunjale kan yoo wa ti wọn yoo jale wọn ni gbangba bayii, ti wọn yoo ja owo nla gba, ti wọn yoo si pa ọlọpaa bii ẹni pa adiẹ.
Eyi ni gbogbo araalu ṣe fẹẹ mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, ati bi ọrọ yoo ti ri. Eyi naa lo si ṣe jẹ itura fun gbogbo eeyan nigba ti awọn redio ati tẹlifiṣan gbe e ni alẹ ọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, 1979, naa pe wọn yoo dajọ awọn adigunjale to pa ọlọpaa meji, to si ṣe ẹkẹta leṣe lọla, iyẹn ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu karun-un, ọdun 1979. Ṣe aye ọjọ naa ko jọ ti asiko yii, ki i ṣe gbogbo eeyan lo ni redio, bẹẹ ni awọn ti wọn ni tẹlifiṣan sile ko to nnkan. Iwe iroyin lo gbayi ju, Daily Times igba naa si ni olori gbogbo wọn. Oun naa si ni gbogbo eeyan n duro de lọjọ keji, bẹẹ loun paapaa ko si ja wọn kulẹ: iroyin idajọ awọn adigunjale naa lo fi ṣaaju iroyin gbogbo. Gadagba ni Daily Times ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu karun-un yii, gbe e pe “ONI LỌJỌ IDAJỌ (TODAY IS DAY OF JUDGMENT),” ti iroyin naa lẹkun-un-rẹrẹ si tẹle e bayii pe:
“Awọn ọkunrin mẹfa kan yoo fẹsẹ ara wọn rin dewaju igbimọ to n gbọ ẹjọ awọn to ba digunjale laaarọ yii, nibi ti wọn yoo ti sọ idajọ wọn fun wọn lori ẹsun pe wọn ja ọgọrin ẹgbẹrun Naira (N80,000) gba. Awọn ọkunrin ọhun – ti meji ninu wọn jẹ ṣọja-to-sa-wale, ti ọkan jẹ ọlọpaa moba – ni wọn fẹsun kan pe wọn ja ọgọrin ẹgbẹrun Naira gba lọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, 1979. Nigba ti wọn n fipa jale yii, wọn yinbọn pa awọn ọlọpaa meji ti wọn ba wọn ṣọ owo ti wọn n gbe lọ naa, bẹẹ ni wọn si ṣe eyi to jẹ dẹrẹba to n wa ọkọ wọn leṣe yannayanna. Ti wọn ba da wọn lẹbi loni-in yii, a jẹ pe wọn yoo yinbọn pa wọn ni gbangba ni. Awọn ti wọn fẹsun ọlọmọ mẹta (ilẹdi-apo-pọ, idigunjale, ati ṣiṣe Sunny Dauda leṣe) kan yii ni Nelson Diefoh, ẹni to ti jẹ ṣọja tẹlẹ, ṣugbọn to sa jade kuro nibẹ lai gbaṣẹ tabi kọwe fiṣẹ silẹ.
“Awọn to ku rẹ ni John Ibekwe to jẹ kuku ati iranṣẹ ni ileeṣẹ Boulos ti wọn ti ja owo gba; William Douglas, oniṣowo kata-kara; William Ogbolu to n ṣiṣẹ lebura; Youpelle Dakuro toun naa jẹ ṣọja to sa wale; ati ọlọpaa moba kan, Lawrence Edemirukevu. Olori olupẹjọ fun ijọba ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tunde Ilọri, sọ pe awọn eeyan naa gbimọ-pọ, wọn si digun jale yii ni ikorita Aromirẹ ati Adeniyi Jones, iyẹn nibi ti ọna mejeeji ti pade ara wọn n’Ikẹja. Lasiko igbẹjọ naa to bẹrẹ ni ọjọ keji, oṣu karun-un, awọn ẹlẹrii mẹtala ni olupẹjọ pe, awọn ọdaran naa ko pe ẹlẹrii, funra tiwọn ni wọn ṣe ẹri ara wọn. Adajọ E. A. Hotonu ni olori igbimọ ẹlẹni-mẹta ti yoo dajọ wọn loni-in yii, awọn meji to si ku pẹlu rẹ ni Ọga ọlọpaa (Chief Supritendent) E. E. Joshua ati Ọgagun (Major) P. O. Kalikume lati ileeṣẹ ologun aami-ṣọja.
“Lọọya mẹta lo duro pẹlu olupẹjọ ijọba, lati le fi idi ẹsun wọn mulẹ, ki awọn adajọ le rohun da. Ṣugbọn awọn adigunjale yii ko gba lọọya, afi awọn meji pere ninu wọn. Oloye J. O. Oniware ni lọọya to duro fun Diefoh ati Edemirukevu, ọmọọṣẹ rẹ to si mu dani lati ran an lọwọ ni Olu Akintunde. Awọn ti wọn jẹrii gbe ijọba lẹsẹ ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Boulos, awọn ọlọpaa ti wọn wadii ọrọ naa, ọkunrin wolii oniṣọọṣi kan, ati ọkunrin fọganaisa kan. Kaṣia ileeṣe Boulos, Israel Falọrọ, ẹni to n gbe owo yii lọ si banki gan-an sọ niwaju awọn adajọ pe irẹsi loun n jẹ lọwọ ninu mọto to n gbe owo yii lọ pẹlu awọn ọlọpaa to n ṣọ ọ nigba ti wahala yii fi de. O ni bi mọto Toyota tawọn ṣe fẹẹ ya mọtọ mi-in to wa niwaju ẹ silẹ bayii, bi awọn adigunjale naa ṣe dana ibọn bolẹ lẹgbẹẹ awọn niyẹn.
“Ẹnikan kan ṣilẹkun mọ mi lẹgbẹẹ piri lojiji ni, lo ba paṣẹ fun mi pe ki n bọọlẹ kia, ki n si doju bolẹ nilẹẹlẹ nibẹ. Ni mo ba ṣe bẹẹ, ko si pẹ ti mo gboju soke ti mo ri i pe ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ owo naa ti ṣubu lati inu mọto, ti ẹjẹ si n ṣe wọru lati ara rẹ. Ẹni keji ẹ naa to jokoo sẹgbẹẹ mi gan-an ti sun gbalaja, ẹjẹ lo n jade lati agbari oun naa.’’ Bi Falọrọ ti wi niyẹn. Maneja ileeṣẹ naa paapaa, Nazih Tabet, nigba ti oun naa n jẹrii niwaju awọn adajọ sọ pe oun ati Falọrọ lawọn jọ ka owo naa, ti awọn si fi i sinu pọtimanto kan, pe ki wọn le lọọ ko owo naa si Backlays Bank, to wa ni Ọba Akran, n’Ikẹja. O ni bii aago mẹjọ aabọ ni wọn jade ninu ọgba awọn, ko si pẹ rara lẹyin naa ti dẹrẹba to wa mọto de pẹlu ẹjẹ ni gbogbo ara rẹ, lo ba sọ ohun to ṣẹlẹ fawọn, n lawọn ba ni ki wọn tete gbe e lọ si ọsibitu, nigba ti Falọrọ de toun naa tun sọ bẹẹ, awọn ni ki wọn gbe oun lọ si tọlọpaa, ko lọọ ṣalaye ọrọ naa fun wọn.
“Fọganaisa ti ọrọ ṣọju ẹ gan-an naa rojọ. Ọgbẹni Samson Adeṣọla ni oju oun lọrọ naa ti ṣẹlẹ, nitori oun ṣẹṣe deta, oun fẹẹ to irinṣẹ oun ni, afi bi oun ṣe bẹrẹ si i gburoo ibọn, nigba toun yoo si wo iwaju loun ri awọn adigunjale naa, n loun ba fẹsẹ fẹ ẹ. Ṣugbọn oun ri wọn nibi ti oun sa pamọ si, oun n wo wọn bi wọn ti yinbọn pa awọn ọlọpaa to wa ninu mọto, ati bi wọn ṣe gbe owo naa sa lọ. Wọn pe Pasitọ Samson Amosun naa ko waa sọrọ, oun naa si ṣalaye pe awọn eeyan naa waa gbadura lọdọ oun, bo tilẹ jẹ pe wọn ko pe ara wọn ni adigunjale, onimọto akẹru ni wọn pe ara wọn, adura ti wọn si ba wa naa ni ojurere ati aanu. Gbogbo ẹjọ ti wọn ro yii lo ni akọsilẹ, eyi naa si ni awọn adajọ yii yoo dajọ wọn le lori. Olupẹjọ ijọba ti ni ko si awitunwi kan ninu ọrọ yii, ki wọn da wọn lẹbi, ki wọn si dajọ iku fun wọn ni.”
Bi iwe iroyin Daily Times ti rojọ ọrọ naa lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu karun-un, 1979 yii ree, eyi gan-an lo si mu ero pọ pitimu niwaju igbimọ naa, wọn fẹẹ gbọ ibi tẹjọ wọn yii yoo fori sọ. Awọn mi-in wa latilẹ okeere, awọn mi-in si wa lati itosi, awọn oniroyin si lọ bii omi, nitori boya ni olokiki-isọnu kan wa ni gbogbo Naijiria nigba naa to ju awọn adigunjale wọnyi lọ.