Ademọla Adejare
Ọjọ Sannde, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2019 to kọja, ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn n pe ni Pasitọ Tunde Bakare ya gbogbo aye lẹnu, nigba to bu ramuramu niwaju ijọ rẹ, to si sọ bayii pe: “Ko si kinni kan ti yoo yi i pada, emi ni n oo gba ipo aarẹ lẹyin Buhari!” Gbogbo eeyan lo ṣe ha, ṣugbọn ọkunrin naa ko ti i pari ọrọ rẹ, o tẹ siwaju, o ni, “Ẹ pariwo rẹ lori oke gbogbo ti ẹ ko ba ti i gbọ tẹlẹ. Mo n sọ fun yin ni awurọ yii o, pe ni ti ọrọ oṣelu orilẹ-ede Naijiria wa yii, Aarẹ Buhari lo wa ni ipo kẹẹẹdogun gẹgẹ bii aarẹ ilẹ wa, ṣugbọn emi ti mo wa niwaju yin yii ni n oo gba ipo kẹrindinlogun gẹgẹ bii aarẹ. Ṣe ẹ mọ pe n ko sọ bẹẹ fun yin ri, mo kan fẹ ki ẹ mọ mi laaarọ yii ni. Ko si ohun to le yi i pada, Buhari ni nọmba fiftin, emi si ni nọmba sistin! Nitori ohun ti mo ṣe wa sile aye gan-an niyi, nitori ohun ti wọn ṣe bi mi niyẹn. Bi Buhari ba ti n lọ, emi ni n oo wọle sipo ẹ!” Bayii ni Pasitọ Tunde Bakare wi.
Nigba to sọrọ naa, yẹyẹ ni ọpọlọpọ awọn eeyan fi i ṣe, paapaa awọn pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, awọn ti wọn ti n reti pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni yoo gba ipo lọwọ Buhari. Wọn ni ọti lo n pa Bakare, pe bi ko ba jẹ ọti oṣelu n pa a ni, yoo mọ pe ọrọ oṣelu ki i ṣe ohun ti eeyan n sọ lori pẹpẹ iwaasu, awọn ti wọn wa loju agbo lo le mọ ohun to n lọ. Ati pe nibi ti iṣẹ ti de ti ọrọ si ti de duro, ko si ẹni to le da Tinubu duro mọ, itakun to ba ni ki erin ma wọdo ni, toun terin lo n lọ. Bakare ko tori ẹ dakẹ ṣaa o, o tun sọ ọrọ bẹẹ naa ninu oṣu keji, ọdun yii, o saa n tẹnu mọ ọn pe oun loun yoo gba ipo lọwọ Buhari, bẹẹ lo tun ṣe ifọrọwanilẹnu wo kan nibẹrẹ oṣu ta a wa yii, orin kan naa lo si n kọ lẹnu, ohun to n wi ni pe oun ṣaa loun wa ni ipo kẹrindinlogun, oun loun yoo gbajọba lọwọ Buhari.
Gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun, ko sẹni to le sọ pato boya Bakare riran ri kinni naa ni o, tabi o n sọ ohun to wa lọkan rẹ jade. Ohun ti awọn ọlọgbọn kan ri ni pe ọrọ naa da a loju pupọ, wọn si n sọ laarin ara wọn pe bi ko ba jẹ o ni ohun ti ajanaku jẹ tẹlẹ ikun, ko ni i ṣe ikun gbentọ siwaju ọlọdẹ pe ko yinbọn lu oun. Ohun to n ya wọn lẹnu ṣaa ni pe pẹlu gbogbo ọrọ to n sọ lẹnu yii, wọn ko ri ibi ti yoo ba wọle bo ti n wi yii, nitori ko si ninu ẹgbẹ oṣelu gidi kan ti eeyan mọ, ko si sọ pe oun n da ẹgbẹ oṣelu toun silẹ, bẹẹ Tinubu ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ti n ba iṣẹ lo rẹbutu. Ni gbogbo asiko naa ni Tinubu ti ko lọ si Abuja, to si n ṣiṣẹ lọ laarin awọn oloṣelu ilẹ Hausa, paapaa awọn to ri i pe wọn sun mọ Buhari daadaa, awọn to si mọ pe bi ọrọ ba di ọrọ ibo didi ninu APC ati ibo apapọ, wọn yoo ṣe bẹbẹ lati ri i pe oun di aarẹ.
Gbogbo eyi ko jẹ ki awọn ọmọ Tinubu gba, wọn kan n wo Bakare bii alawada akọ ni, wọn ni bo ba ya a, yoo pada si ṣọọṣi rẹ, yoo maa ba iṣẹ Oluwa to waye ẹ waa ṣe lọ. Ṣugbọn Bakare mọ ohun to n ṣe, nitori ki i ṣe akọkọ niyi ti wọn yoo fi ọrọ oṣelu lọ ọ, akọkọ kọ niyi ti yoo ba wọn sun mọ ile aarẹ. Ni gbara ti Aarẹ Umoru Yar’Adua bẹrẹ aiyaara ni 2009, to si di pe aiyaara naa n le si i, ti awọn ti wọn n ṣejọba si n purọ faraalu, ti wọn ko fẹ kawọn eeyan mọ ohun to n ṣẹlẹ, Bakare wa ninu awọn ti wọn jade, awọn ni wọn si wa lẹyin Goodluck Jonathan titi ti tọhun fi pada waa gbajọba, ko tilẹ too di pe Yar’Adua ku ni 2010 rara. Nitori eyi, pẹlu awọn idi mi-in, nigba ti Buhari yii kan naa yoo du ipo aarẹ lọdun 2011, Bakare lo fi ṣe igbakeji rẹ, o ni ẹni ti ọkan oun mu ree, ki awọn jọ lọ sile ijọba. Ṣugbọn Buhari ko wọle, ni Bakare ba pada si ṣọọsi.
Ohun ti awọn ti wọn wa lẹyin Tinubu n ro ree, ti wọn fi ni Bakare ko le ri ọwọ mu nibikibi. Ṣugbọn awọn kinni kan ṣẹlẹ laarin ọjọ meloo kan sẹyin to fi han pe o ṣee ṣe ki ọrọ ti Bakare n sọ wa si imuṣẹ o. Bi nnkan ti ṣe n lọ yii, afaimọ ni Buhari ko ti pinnu lati fi Pasitọ Bakare yii rọpo Bọla Tinubu. Idi ni pe bi Bakare ti n sun mọ ile ijọba lẹnu ọjọ mẹta yii, bẹẹ ni Tinubu n jinna sile ijọba si i, bo tilẹ jẹ pe wọn ko pariwo ọrọ naa sita. Akọkọ ni ti ọgbọn ti wọn fi yẹ oju Tinubu l’Abuja. Ki i ṣe pe wọn sọ pe awọn fẹẹ le e, wọn ni ki APC ṣeto, ki awọn aṣaaju ẹgbẹ naa pada si adugbo wọn, ki kaluku gba ipinlẹ rẹ lọ, ki wọn lọọ di ibẹ mu giri, ki wọn le yanju gbogbo iṣoro to ba wa nibẹ ko too di pe ibo kankan de rara. Loootọ Tinubu ko gba pe nitori oun ni wọn ṣe ṣe ofin yii, ṣugbọn awọn ti wọn mọdi oṣelu ni wọn fọgbọn yẹju ẹ ni, nitori gulegule ẹ lọna Abuja ti dinku bayii, ẹẹkọọkan lo ku to n lọ.
Ọna keji ni ti ẹjọ rẹ ti wọn n gbe dide bayii, ẹjọ ileeṣẹ Alpha Beta, ileeṣẹ Tinubu to n gba owo-ori fun ijọba Eko lati ọdun 2002, titi di asiko ti a wa yii. Bo tilẹ jẹ pe Tinubu n sọ pe ileeṣẹ naa ki i ṣe toun, awọn ti wọn n wadii ọrọ ti wadii kan awọn iwe oriṣiiriṣii to fihan pe ki i ṣe pe ileeṣẹ naa jẹ ti Tinubu nikan kọ, ọpọlọpọ owo ti ileeṣẹ naa n pa, ninu banki Tinubu tabi ti awọn ti Tinubu ba mọ ni owo naa maa n wọlẹ si. Ati pẹlu, ẹni to da ileeṣẹ naa gan-an silẹ, to lọọ ba Tinubu pe ko ran oun lọwọ lori rẹ, ko too di pe Tinubu ni ki awọn jọ maa ṣe, ti tu ọpọ aṣiri fun awọn ti wọn n wadii, atawọn ti wọn jẹ ọta oun Tinubu, o si jọ pe ijọba fẹẹ tọpinpin ọrọ naa, ki wọn le ri Tinubu mu. Ọrọ ẹjọ yii wa nibẹ ni wahala iwọde ti SARS bẹrẹ ni Eko, ohun ti awọn kan si kọkọ lọọ gbe ba Buhari ni pe Tinubu mọ nipa ẹ, wọn lo fẹẹ fi kan ijọba Buhari labuku ni.
Ni tododo, ALAROYE gbọ pe asiko yii ko daa fun Tinubu lọdọ Buhari ati awọn ọmọ rẹ, eleyii si pẹlu ohun to jẹ ki awọn agbaagba ẹgbẹ APC kan lati Eko gbera lọ si Abuja lọsẹ to kọja. Bisi Akande lo ṣaaju wọn lọ. Oluṣẹgun Ọṣọba wa nibẹ, bẹẹ si ni Tajudeen Olusi ati Abayọmi Finnih. Gbogbo awọn yi pata, eeyan Tinubu ni wọn, nigba ti wọn si ṣepade naa, wọn ko le sọ idi ọrọ naa fẹnikan. ALAROYE fimu finlẹ gbọ pe ọrọ naa ni i ṣe pẹlu ti Tinubu, awọn eeyan naa n mura lati yanju ohun yoowu to ba wa laarin Buhari ati ọrẹ wọn, ati lati ṣalaye pe Tinubu ko jẹ lọwọ si ohunkohun lati ba ijọba rẹ jẹ, ko si fi Tinubu silẹ ko jẹ ko du ipo aarẹ to fẹẹ du. Ko sohun to fa iru ijade ojiji yii ju pe Tinubu ri i bi wọn ṣe fọgbọn ti oun sita l’Abuja, ati pe ete kan ti n lọ. Ete to si n lo naa ni pe Tunde Bakare ti gbori wọle sọdọ Buhari, nitori bi Tinubu ti bọ si Eko ni Bakare gunlẹ siluu Abuja.
ALAROYE gbọ pe ile ijọba kan ni wọn fẹẹ fi Bakare si tẹlẹ, oun lo kọ pe ki wọn jẹ ki oun maa gbe ile adani, lẹsẹkẹsẹ ni wọn si ti wa ile naa fun un nibẹ. Bi a ti n wi yii, Abuja ni Bakare wa lati ọjọ Aje to kọja yii, ẹsẹ kan Eko, ẹsẹ kan Abuja, lo si ku to n ṣe. Awọn ti wọn sọrọ yii fun ALAROYE ni ọpọlọpọ iṣẹ ni Buhari ti fa le ọkunrin naa lọwọ, to si paṣẹ ki awọn oludamọran ati awọn minisita mi-in paapaa maa lọọ ri i lori ọrọ to ba takoko nidii iṣẹ wọn. Nigba ti Bakare ki i ṣe igbakeji aarẹ, ti ko si gba iṣẹ ijọba, to waa ko lọ si Abuja, to si jẹ Buhari funra ẹ lo ranṣẹ pe e, ohun ti awọn eeyan ṣe n sọ pe boya ni kinni naa ko ti ri bi Bakare ti n sọ ọ, pe afaimọ ko ma jẹ Buhari ti pinnu lọkan ara rẹ lati fi i rọpo Tinubu. Ọgbọn ti wọn waa fẹẹ da si i lẹnikan ko ti i mọ. Boya wọn yoo mu Bakare wọ inu APC ni o, tabi eto mi-in wa ti wọn yoo ṣe fun un, ko sẹni to mọ, ohun tawọn Tinubu funra wọn yoo si ṣe, ko sẹni to le sọ.