Tori temi ni Akeredoku ṣe yọ kọmisanna eto idajọ ati igbakeji olori awọn aṣofin- Ajayi

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Igbakeji Gomina Ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi ti bu ẹnu atẹ lu yiyọ ti wọn yọ kọmisanna feto idajọ, Adekọla Ọlawọye, ati igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin, Irọju Ogundeji, nipo laarin ọjọ kan pere sira wọn.
Ajayi sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Allen Soworẹ, lọsan-an ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
O ni tawọn eeyan ko ba gbagbe, ogunjọ, osu kẹwaa, ọdun 2020, loun kọkọ pariwo sita pẹlu asiri to tu soun lọwọ nigba naa pe Akeredolu atawọn alatilẹyin rẹ kan fẹẹ ṣe ayederu iwe ifipo silẹ lorukọ oun.
O ni ariwo yii ni wọn gbọ ti wọn fi jawọ ninu erongba ati fi tipatipa yọ oun nipo lẹyin eto idibo gomina to waye losu to kọja.
Ajayi ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, ni gomina fipa da kọmisanna rẹ duro, ti awọn aṣofin naa si tun jisẹ to ran wọn nipa yiyọ igbakeji olori ile nipo lọna to lodi sofin lọjọ keji.
Igbakeji gomina ọhun ni ṣe l’Arakunrin mọ-ọn-mọ fẹẹ sọ ẹka eto idajọ ati ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo di yẹpẹrẹ, ko le raaye yọ oun nipo gẹgẹ bii ipinnu rẹ.
O ni oun n fi asiko naa sọ fawọn araalu pe Akeredolu atawọn eeyan rẹ tun ti n gbero ayederu ibọwọlu awọn aṣofin lọnakọna, eyi ti wọn fẹẹ fi yọ oun nipo tipatipa.

Leave a Reply