Ibo aarẹ 2023: Tinubu ati Fayẹmi wọ ṣokoto ija

Bi kinni kan ba wa to wu Gomina ipinlẹ Ekiti laye yii ju lọ, ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria ni. Ọkunrin naa fẹran ko di aarẹ ilẹ wa, ohun teeyan ko ti i mọ ni bi ọrọ naa ṣe ka a lara to, boya yoo du ipo naa ni 2023 ni, tabi yoo sinmi diẹ lẹyin to ba ṣe gomina tan. Ohun to daju ṣaa ni pe o wu Fayemi ko di aarẹ. Nitori pe ko ti i fi bẹẹ dagba, awọn kan ni ko duro diẹ na, ko ma ti i jade pe oun fẹẹ du ipo aarẹ. Awọn ti wọn ni ko ma ti i jade yii ni bi Yoruba tabi Ibo ba wa, to lo ọdun mẹjọ, ti Hausa mi-in wa, to lo ọdun mẹjọ, koda ko jẹ lẹyin ọdun mẹrindinlogun ni ipo naa too kan an, yoo ṣẹṣẹ le bii ọdun meji ni aadọrin ni, eyi ko si ti i buru ju fun ẹni to ba fẹẹ ṣe aarẹ ilẹ wa. Ṣugbọn awọn ti wọn fẹ ko di aarẹ ni bayii bayii sọ pe ọdun mẹrindinlogun ti pẹ ju, bo ba fi le jẹ ki kinni naa bọ lasiko yii, ko tun tẹ ẹ lọwọ mọ niyẹn.

Awọn yii gbagbọ pe asiko yii ni irawọ rẹ n tan, nitori awọn to mọ lo wa nile ijọba l’Abuja, ipo pataki loun naa si di mu gẹge bii alaga ẹgbẹ awọn gomina, ko si si ohun ti ko le fi ipo naa ṣe. Yatọ si ti ipo to wa, ọkan ninu awọn ti Aarẹ Muhammadu Buhari n gbọrọ si lẹnu ni, nitori pe ọkan ninu awọn to ṣiṣẹ rẹpẹtẹ fun un nigba ti yoo wọle ibo ni 2015 ni. Ati pe awọn eeyan nla mi-in tun wa ti wọn sun mọ Buhari, ti wọn si lagbara ninu ijọba yii, to jẹ ohun ti wọn n sọ ni pe awọn le ti Fayẹmi lẹyin to ba jade lati du ipo naa. Ṣugbọn ẹni kan wa ti gbogbo aye ti mọ pe oun lo fẹẹ du ipo yii, ọga agba pata lo si jẹ fun Fayẹmi, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni. Gbogbo eto pata lo ti ṣe kalẹ, bo si tilẹ jẹ pe ni gbogbo igba ni i sọ sita pe oun ko sọ fẹnikan pe oun fẹẹ du ipo aarẹ, sibẹ, awọn ọmọ eriwo n ṣiṣẹ lọ lai sinmi.

Ṣe Fayẹmi ko mọ eyi ni, abi nigba wo lọrọ pe oun naa yoo du ipo aarẹ ja si i ninu. Titi di igba ti Fayẹmi pada di gomina Ekiti lẹẹkeji, ko ti i ni in lọkan pe oun yoo du ipo aarẹ, tabi pe oun le du ipo naa, bi oun ba si fẹẹ du u rara, ko ni i jẹ lẹyin Buhari yii, ṣe gbogbo wọn naa ni wọn ṣaa mọ pe ibi ti oju Tinubu wa niyẹn.  Loootọ lati 2016 ni ija ti fara han laarin Tinubu atawọn kan ninu awọn ọmọleyin rẹ, awọn ti wọn n sọ pe Tinubu ko fẹ ki awọn ṣoriire, o fẹẹ sọ ara rẹ di Ọlọrun, nitori pe ọpọ awọn ti wọn di minisita lẹyin Buhari ni 2015, ki i ṣe ọwọ Tinubu ni wọn fi debẹ, koda, ko fẹ ki Buhari yan awọn mi-in ninu wọn. Ibinu ọrọ yii ja ran-in ran-in debii pe ni ibẹre ọdun 2017, ninu oṣu kin-in-ni, ọdun naa, niluu Ibadan, Fayẹmi ati Ibikunle Amosun woju Rauf Arẹgbẹṣọla, nigba to sọ pe ọdalẹ lawọn mejeeji, pe awọn ni wọn fẹẹ dalẹ Tinubu.

Wọn fi ọgbọn yanju ọrọ naa ti ko fi di ariwo, ṣugbọn nnkan ko gun rege ni aarin wọn mọ, paapaa nigba to jẹ awọn gomina ati oloṣelu ilẹ Hausa mi-in ti wọn koriira Tinubu lawọn Fayẹmi n ba ṣe. Ni 2018 ti Fayẹmi yoo tun du ipo gomina, ọrọ naa rọ diẹ, nitori yatọ si pe Tinubu lọ si Ekiti lati kampeeni ibo fun Fayẹmi, o jẹ ki awọn eeyan mọ pe ọmọ oun ni, ko si si ija kankan laarin awọn. Ṣugbọn awọn eeyan mọ pe ki i ṣe inu Tinubu lo daa debẹ, ohun to n wa lo sọ ọ di eeyan jẹẹjẹ, nitori oun naa ti mọ pe agbara to wa ni ọwọ awọn Fayẹmi niluu Abuja ju toun lọ, bẹẹ Abuja yii ni gbogbo agbara wa. Ko waa pẹ rara ti Fayẹmi wọle lẹẹkeji, to si bẹrẹ iṣẹ bii gomina ti nnkan fi yipada biri, toun naa si bẹrẹ si i ri ara rẹ bii alagbara, ati pe ko si ohun to buru nibẹ bi oun naa ba du ipo aarẹ. Awọn kan ni wọn sọrọ naa si i leti.

Ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹta, ọdun 2019, ni wọn kọkọ sọrọ naa si i leti, latigba naa si ni nnkan ti yipada. Awọn agbaagba ilẹ Yoruba meji ni wọn ba a sọrọ lẹẹkan naa, nibi kan naa, nijọ kan naa. Ohun ti wọn si sọ ni pe awọn ri i bii aarẹ Naijiria, awọn si mọ pe yoo ṣe iṣẹ naa daadaa bo ba di aarẹ. Iranti aadọfa (110) ọdun ti wọn bi Ọbafẹmi Awolọwọ ni wọn n ṣe l’Ekiti, ti wọn waa ko awọn agbaagba ilu jọ. Nibẹ ni Oloye Ayọ Fasanmi to ṣẹṣẹ ku ku yii ti kọkọ sọ pe Fayẹmi lo yẹ ni ipo aarẹ Naijiria ni 2023, to si sin in ni gbẹrẹ ipakọ pe gbogbo agbara to ni gẹgẹ bii ọmọ ati aṣoju ilẹ Ekiti ni ko fi ja, ko si i ri pe oun loun di aarẹ. Fasanmi ni ẹni yoowu to ba ni awọn ẹbun ati amuyẹ to dara bii ti Awolọwọ ni ki gbogbo ọmọ Yoruba gbaruku ti ni 2023, ati pe Fayẹmi lo ni iru awọn abuda yii ju lọ, gbogbo ohun ti Awolọwọ si fẹẹ ṣe fun Naijiria ni Fayẹmi le ṣe.

Bi Fasanmi ti sọrọ ni aṣaaju apapọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba gbogbo, Ọjọgbọn Banji Akintoye, la ọrọ naa mọlẹ, o ni,  “Ni ọdun 2023, awa Ekiti fẹẹ ṣe ohun ti a ko ṣe ri, a fẹẹ jade lati du ipo aarẹ Naijiria, nitori ọgbọn ati imọ Ekiti lo ku to le ko Naijiria yọ ninu ibi ti a ha si yii, gbogbo ọgbọn ati imọ ti a si nilo yii lo wa ninu Kayode (Fayẹmi) o mọ ohun to yẹ ko ṣe ti yoo fi yi orilẹ-ede wa pada sibi to dara.” Ni gbangba ni Fasanmi ti sọrọ, ni gbangba naa ni Akintoye ti ju tirẹ naa si i. Ko si sẹnikan to ba wọn jiyan, wọn ni ọrọ gidi lo tẹnu awọn agba ilẹ Yoruba mejeeji jade. Lati ọjọ naa ni nnkan si ti yipada loootọ, ti Fayẹmi ti ro pe bi oun ba mura si i loootọ, oun le di aarẹ ni 2023. Awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Tinubu ti wọn gbọ ọrọ naa ko dakẹ, rara fun wọn taara. Ni bii oṣu keji lẹyin iyẹn ni iwe alẹmọgiri akọkọ si jade pe Tinubu yoo du ipo aarẹ ni 2023.

Lati fi han pe ọga ni masita loootọ, posita ti wọn lẹ pẹlu awọn aworan yii kaakiri ilẹ Yoruba lọwọ kan naa, kinni naa si tan ka gbogbo ibi. Kia lawọn oloṣelu ilẹ Hausa ti gbogun ti Tinubu, ti wọn si n bu u ni mẹsan-an mẹwaa pe ki lo n ba kiri, nigba ti Buhari ko ti i ṣe ọdun kan ti oun ti bẹrẹ si i pariwo pe oun fẹẹ di aarẹ. Ni Tinubu naa ba rọri pada sẹyin, o ni oun ko mọ kinni kan nipa ẹ, awọn ti oun ko mọ lo n ṣe bẹẹ, igba to si ya, wọn ni awọn PDP ni, wọn fẹẹ fi daja silẹ ninu APC ni. Ṣugbọn ọrọ naa ko jẹ ọpọlọpọ eeyan, wọn mọ pe iru awọn nnkan bẹẹ ko le jade ki Tinubu ma mọ si i. Ninu awọn ara ilẹ Hausa ti wọn koriira Tinubu ati iṣẹ ọwọ rẹ ni El-Rufai, ohun ti awọn eeyan si n ro nigba to n sọrọ si Tinubu kasakasa ni pe o fẹẹ dupo aarẹ ni. Ṣugbọn pẹlu bo ṣe n bu Tinubu to yii, awo loun ati Fayẹmi, ọrẹ wọn fẹrẹ ju ti ọmọ iya meji lọ.

Gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu wọn, wọn jọ n ṣe e ni, awọn ni wọn si mọ bi wọn ti ṣe le Adams Oshiomhole lọ, ti wọn gba ẹgbẹ kuro lọwọ rẹ, bẹẹ olori awọn aṣoju Tinubu ninu ẹgbẹ naa niyẹn. Bi APC ṣe wa bayii, awọn El-Rufai, Fayẹmi ati Amosun pẹlu awọn mi-in ti wọn fẹẹ gba gbogbo agbara lọwọ Tinubu ni wọn ni ẹnu nibẹ ju lọ. Ohun tawọn eeyan ṣe ro pe El-Rufai lo fẹẹ jade du ipo naa ree. Afi bo ṣe bọ sita ni bii ọsẹ mẹta sẹyin, to ni oun ko ni i dupo aarẹ, eeyan lati ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo lo gbọdọ dupo naa, oun ko ni i ti ọmọ ilẹ Hausa kan lẹyin ni 2023 lati di aarẹ. Nibi yii lọrọ ti ye awọn eeyan, wọn ni o jọ pe Fayẹmi ni ọkunrin naa n ṣiṣẹ fun, ti Fayemi yoo jẹ purẹsidenti, ti oun El-Rufai yoo si jẹ igbakeji fun un. Awọn kan ti ro pe iṣẹ Pasitọ Tunde Bakare lo n ṣe tẹlẹ, ṣugbọn iyẹn ko si ninu ẹgbẹ APC, ko si ti i si ẹni to mọ ẹgbẹ oṣelu to n ṣe gan-an.

Awọn gomina paapaa n leri kiri pe lara awọn eeyan awọn, iyẹn ninu awọn gomina lo yẹ ki ipo aarẹ bọ si lọwọ bi wọn ti ṣe e laye Yaradua ati Jonathan, bi eleyii ba si fi ri bẹẹ, ko ti i si gomina kan to yọju to ju Fayẹmi lọ. Nitori ẹ ni ko ṣe ya awọn eeyan lẹnu nigba ti alaga ijọba ibilẹ Ikẹrẹ, Fẹmi Ayọdele, gbe posita nla jade, to si fọn ọn kaakiri sori ẹrọ ayelujara ẹ, o ni Fayẹmi ni yoo di aarẹ Naijiria ni 2023, ki gbogbo Yoruba ti i lẹyin. Loootọ awọn aṣofin ipinlẹ naa binu, ti wọn yọ ọ kuro nipo, ti ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ Fayẹmi si sọ pe ọga oun kọ lo ran an niṣẹ, ṣugbọn eyi naa ko jọ awọn eeyan loju, nitori bi Tinubu naa ti n ṣe ree. Titi di asiko yii, ko ṣaa ti i jade pe oun yoo du ipo aarẹ ni 2023, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan rẹ n ba iṣẹ lọ. Nibi ti ọrọ de bayii, ohun to han gbangba ni pe Tinubu ati ọmọ rẹ, Fayẹmi yoo wọ ṣokoto ija, ẹni ti yoo gbe ẹni kan ṣubu la o ti i le sọ.

Leave a Reply