Ibo abẹle APC: Ọkan ninu awọn aṣoju ku s’Abuja

Jọkẹ Amọri
Ọkan ninu awọn aṣoju to waa dibo lati yan ẹni to maa dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC to wa lati ipinlẹ Jigawa, Alaaji Isa Baba Buji ti ku o. Ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgọta yii ni igbakeji alaga ẹgbẹ naa ni iha Guusu ipinlẹ ọhun.
Niṣe lọkunrin naa ṣubu lulẹ lojiji lọfiisi ipinlẹ naa to wa niluu Abuja lasiko to n mura lati maa lọ si ibi ti eto idibo abẹle naa yoo ti waye. Oju-ẹsẹ ni wọn sare gbe ọkunrin naa digbadigba lọ si ileewosan, ṣugbọn niṣe ni awọn dokita sọ pe oku lẹni ti wọn gbe wa naa, o ti ku ki wọn too gbe e de ọsibitu. Awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa sọ pe o jọ pe ọkan rẹ lo daṣẹ silẹ.
Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn aṣoju naa ati mọlẹbi ọkunrin to ku lojiji naa/

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: