Jọkẹ Amọri
Gomina ipinlẹ Sokoto, to tun jẹ ọkan ninu awọn oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, ti sọ pe oun ti juwọ silẹ fun Alaaji Atiku Abubakar toun naa n dije fun ipo yii kan naa.
Ni papa iṣere MKO Abiọla, niluu Abuja, nibi ti eto idibo naa ti n lọ lọwọ, lo ti sọ eleyii di mimọ. O ni lẹyin toun ti ṣe ọpọlọpọ ifikunlukun pẹlu awọn eeyan kan loun gbe igbesẹ yii.
O waa rọ awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn dibo wọn fun Atiku Abubakar.
Bakan naa ni ọkan ninu awọn oludije naa, Dokita Nwachukwu Anakwenze, naa ti sọ pe oun ti juwọ silẹ fun gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, toun naa jẹ oludije yii. Bẹẹ loun pẹlu rọ awọn alatilẹyin rẹ lati dibo wọn fun Wike.