Ibo gomina l’Ekiti: Ṣẹgun Oni jawe olubori ni wọọdu rẹ

Taofeek Surdiq
Ibo okoolerugba o din meji (218), ninu ibo ojilenigba o le meji (242), ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Oloye Ṣẹgun Oni, fi gbẹyẹ lọwọ awọn oludije ẹgbẹ rẹ ni wọọdu idibo rẹ to wa ni Wọọdu kẹrin, Yuniiti kẹfa, ni agbegbe Ọgbọn Iro, Ifaki, nijọba ibilẹ Ọyẹ Ekiti.
Ida aadọrun-un ninu ọgọrun ibo lo ni yii, nigba ti ẹni to tẹle e lẹyin lati ẹgbẹ oṣelu APC, Biọdun Oyebamiji, ni ibo mẹẹẹdogun, ti ọmọ ẹgbẹ APP ni ibo mẹta pere, PDP ni ibo meji, nigba ti ẹgbẹ NNPP ni ibo meji.

Leave a Reply