Ibọn ṣọja pa janduku meji, nibi ti wọn ti n fehonu han nitori akẹkọọ ti mọto pa ni Waasinmi

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n sọrọ lori rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Waasinmi, loju ọna marosẹ Eko si Abẹokuta, l’Ọjọbọ, Tosidee, one yii. Nitori yatọ si Mercy John Godwin ti mọto pa lasiko to n lọ sileewe, awọn janduku meji mi-in ba iṣẹlẹ naa rin.

Ibọn ṣọja lo pa wọn nibi ti wọn ti n fiku Mercy jale, ti wọn n da awọn to n kọja lọ lọna, ti wọn si tun di oju ọna marosẹ naa pa.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ Ọgbẹni Tunde Ọjẹṣina tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe ṣalaye ni pe Mercy to wa ni kilaasi keji nileewe Girama United Comprehensive High School, Osiponri, nitosi Waasinmi, n lọ sileewe rẹ laaarọ Ọjọbọ, ọjọ kọkanla, oṣu keji, yii ni.

Asiko to fẹẹ sọda titi ni bọọsi kan ti wọn pe ni Previa, padanu ijanu ẹ, bo ṣe tẹ Mercy, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun, pa niyẹn.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ lawọn eeyan to wa nitosi bẹrẹ ẹhonu, a gbọ pe awọn akẹkọọ ileewe naa paapaa bọ soju ọna yii, ti wọn n binu sohun to ṣẹlẹ, ti wọn si da sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ silẹ pẹlu.

Eyi lo n lọ lọwọ tawọn janduku fi gba a mọ awọn akẹkọọ lọwọ, lo ba di pe wọn dana sun mọto to pa Mercy, wọn bẹrẹ si i ba awọn mọto to n lọ jẹẹjẹ wọn jẹ, bi wọn ṣe n fọ gilaasi ọkọ ni wọn n le awọn ero to wa ninu wọn bọ silẹ, ti wọn n gba foonu, gbowo lọwọ wọn.

Ikọ alaabo Skynet Rescue Corps, to wa sibẹ lati ṣaajo, niṣe ni wọn kọ lu wọn, ti wọn ṣe ọga wọn, Ọgbẹni Kẹhinde Adedigba leṣe. Bakan naa ni awọn MTD (Motor Traffic Department) to wa lati Itori lati gbe oku Mercy kuro nibẹ paapaa fori gba ada lọwọ awọn ọmọ ganfe yii, mẹrin ninu wọn lo n gba itọju lọwọ nileewosan nigba ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

A tilẹ gbọ pe ọkunrin kan to n kọja lọ jẹẹjẹ rẹ naa gba ibọn lọrun lasiko rogbodiyan naa, ileewosan loun pẹlu balẹ si. Ibọn awọn ọlọpaa to wa lati Itori lati pẹtu saawọ yii la gbọ pe o ba a naa lọrun.

Nibi ti wọn ti n fa wahala ọhun lọwọ lawọn ṣọja kan ti n kọja, ṣugbọn eṣu ti yoo ṣe awọn to n fa ijangbọn yii, ti wọn dọdọ awọn ologun ọhun, ni wọn ko ba fẹẹ gbe igi ti wọn fi di oju ọna kuro, wọn ni ṣọja kankan ko ni i kọja.

ALAROYE gbọ pe awọn ṣọja naa ko kọkọ fẹẹ ba wọn ṣaroye kankan, wọn kan paṣẹ fun wọn pe ki wọn ko wahala wọn kuro ni titi ni. Ṣugbọn nibi ti wọn ti n ba wọn sọrọ lọwọ lawọn kan ti bẹrẹ si i juko lu mọto awọn ṣọja, ti oko si n ba awọn ologun ti ko gberegbe, wọn ni bi wọn ṣe yinbọn niyẹn. Ibọn naa lo ba meji ninu awọn alajangbila yii, ti wọn dagbere faye loju-ẹsẹ.

Awọn eeyan ṣi wa nileewosan kaakiri awọn agbegbe yii ti wọn n gba itọju nitori ikọlu naa, bo tilẹ jẹ pe rogbodiyan to ṣẹlẹ latari iku Mercy John ti rọlẹ pata, ti alaafia si ti pada sagbegbe Waasinmi ati Itori.

Leave a Reply