Ibọn ni ọlọpaa ti mo fẹ fi maa n dẹru ba mi, mi o fẹ ẹ mọ – Iyabọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igbeyawo ọlọdun mẹfa to wa laarin ọkunrin ọlọpaa kan, Richard Donald, ati iyawo ẹ, Iyabọ Donald, ti wa sopin.

Iyawo, Iyabọ, lo pẹjọ si kootu ibilẹ Ọjaa’ba, n’Ibadan, pe Richard ti maa n lu oun ju, pabanbari ibẹ si ni bi ọkunrin ọlọpaa móbà naa ṣe maa n fi ibọn dẹruba oun ninu ile, to si maa n leri lati yinbọn pa oun danu.

Obinrin to pera ẹ loniṣowo yii ṣalaye pe “Ko si ifọkanbalẹ kankan fun mu lati ọdun mẹfa ta a ti fẹra, ẹjọ lonii, ija lọla ni.

“Iṣẹ ọlọpaa lo n ṣe, ṣugbọn o ya mi lẹnu pe emi iyawo ẹ gan-an lo waa sọ di ọdaran to maa n ba fa wahala ninu ile lojoojumọ. Ọrọ ti ko to nnkan lo maa mura ija si, yoo si lu mi bii igba ti oun atawọn ọlọpaa ẹgbẹ ẹ ba n lu ọdaran ni teṣan ni. Nigba mi-in, yoo yọ ibọn si mi, aa maa fi ibọn le mi kiri inu ile pe oun maa yinbọn pa mi danu.

“Igba kan wa to ti emi atawọn ọmọ wa mejeeji mọta, to jẹ pe oun nikan lo da sun inu ile lọjọ yẹn.

“Ọpọ igba ti mo ba wa ninu ile pẹlu ẹ, pẹlu ibẹrubojo ni mo fi maa n ba a gbe nitori wahala to maa n ba mi fa lojoojumọ. Bi mo ba tun jade nile naa bayii, ẹru ati wọle pada yoo maa ba mi ni nitori mi o mọ iru wahala to tun maa ba mi fa nigba ti mo ba de. Bẹẹ, alaifẹkan-an-an-ṣe ọkunrin ni, ki i tọju awọn ọmọ debi to maa tọju mi.”

Olupẹjọ yii ko ti i sọrọ ẹ tan ti iya kan, ẹni to pada ṣafihan ara ẹ gẹgẹ bii iya olupẹjọ (Iya Iyabọ) fi nawọ soke, o loun ni alaye kekere kan lati ṣe fun ile-ẹjọ kó le ran wọn lọwọ lati mọ bi wọn ṣe maa da ẹjọ naa.

Nigba ti iya naa yoo bẹrẹ ọrọ, o ni oun ko tori idi meji wa si kootu bi ko ṣe lati ri i pe ile-ẹjọ fopin si igbeyawo ọmọ oun pẹlu ọlọpaa to n fẹ ni nitori ọdaju eeyan to si le paayan lokunrin naa.

Leave a Reply