Idajọ iku lo yẹ kijọba maa fun apaniṣowo atawọn to ba kowo jẹ-Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo tilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti gba Aarẹ Muhammadu Buhari nimọran pe ọna abayọ kan ṣoṣo ti orileede yii ko fi ni i fọ si wẹwẹ ni ki Aarẹ ri i pe oun pin in daadaa, oun si fun ẹya kọkọkan ni ohun to tọ si wọn lai ṣegbe tabi gbe lẹyin eya mi-in lori ọrọ pinpin awọn ipo tabi aaye to ba ṣi silẹ ni Naijiria.

Ọba Akanbi ni ki Buhari pin awọn ipo tabi aaye to ba ṣi silẹ nieeṣẹ ijọba apapọ ni dọngba-n-dọgba. O rọ Buhari lati wẹyin wo, ko ṣe akiyesi awọn eeyan to ti yan sipo, ko si ṣe atunṣe nibi to ba ti yẹ. O ni eyi ni ọkan ninu ọna lati mu ki okun iṣọkan Naijiria yi da-in-dan-in si i, ki iṣọkan wa si le duro.

Ọba Akanbi sọrọ yii niluu Abuja, nibi ifilọlẹ iwe mẹrin ti agbẹjọro agba kan Amofin Aminu Kayọde Aliu kọ.

  Bakan naa ni ọba yii rọ awọn ọmọ orileede yii lati fẹran ara wọn, ki wọn si wa ni iṣọkan. O tun koro oju si bi awọn eeyan ṣe n dẹyẹ si ẹya Fulani, o rọ awọn ọmọ orileede yii lati nifẹẹ ara wọn lai fi ti ẹya, ẹsin ede tabi ẹgbẹ oṣelu ti iru ẹni bẹẹ n ṣe.

O waa rọ ijọba lati ṣagbeyẹwo awọn iwa ojududu ti ko ba aye ode oni mu mọ ti wọn ba n ṣe. Bẹẹ lo rọ awọn ọdọ lati fi suuru ati ọna to tọ beere ohun ti wọn ba fẹ.

Nigba to n sọrọ nipa ọrọ awọn Fulani darandaran, Oluwoo ni a jogun wahala awọn Fulani ni, a si pa wọn ti sinu igbo fun ọdun pipẹ, bẹẹ ni ohun amayedẹrun jinna si wọn. Eyi lo mu ki ọpọlọpọ wọn da bii maaluu ti wọn n sin, a si waa n ba wọn ja, nnkan meji ni, ninu ka pa gbogbo wọn patapata tabi ka fi ifẹ han si wọn.

Bakan naa lo tun gba ijọba nimọran pe ki wọn maa dajọ iku fun awọn apaniṣowo atawọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ba ti gba mu fun ẹsun ikowojẹ tabi iwa ibajẹ kan.  Oluwoo kọminu si bi iwa awọn apaniṣowo ṣe pọ kaakiri lorileede yii. O ni nipa pipa awọn eeyan yii yoo mu ki ilẹ Naijiria wa laarin awọn orileede to ti goke agba lagbaaye.

O fi kun un pe gbogbo awọn orileede to ti goke agba, ateyi to ṣẹṣẹ n goke ni lati pasẹ ijiya to gbopọn fun awọn oniwa ibajẹ.

 

Leave a Reply