Idi tawa Hausa to n gbe l’Ọṣun ṣe pinnu lati ṣatilẹyin fun saa keji Oyetọla ree – Alhaji Umar

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn ẹya Hausa to n gbe kaakiri nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe gbọingbọin lawọn wa lẹyin Gomina Gboyega Oyetọla fun idibo saa keji rẹ lori aleefa.

Nigba ti agbẹnusọ wọn, Alhaji Umar Kotonkoro, n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, oṣẹ yii, lo ṣalaye pe iwa irẹlẹ ati ikonimọra ti awọn ri ninu aye gomina lo fa a ti awọn fi ṣepinnu naa.

Umar ṣalaye pe latigba ti Oyetọla ti dori aleefa, awọn ko bẹru lati da iṣẹ pọ mọ ẹnikẹni nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni awọn ko gbe ninu ifoya rara gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ miiran.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Lorukọ gbogbo awọn Sheriki Hausa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, a n fi atilẹyin wa han fun iṣejọba ẹgbẹ APC labẹ Gomina Isiak Adegboyega Oyetọla.

“A n sọ ọ pẹlu igboya pe a ni igbagbọ kikun ninu iṣejọba Gomina Oyetọla, a si ti ṣetan lati ti i lẹyin titi ti yoo fi rọwọ mu ninu idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun 2022.

“Oniruuru idagbasoke lo ti ba ẹya Hausa labẹ ijọba Oyetọla, eyi ti ko ti i si iru rẹ ri, bẹẹ ni ko fi ọrọ aabo dukia ati ẹmi wa ṣere rara. Oun lo jẹ ka mọ pe o ṣee ṣe fun olori kan ni Naijiria lati ko gbogbo eeyan mọra lai fi ti ẹya ati ẹsin ṣe.

“Oyetọla ti ṣafihan iwa otitọ, iṣododo, ipamọra ati akoyawọ, idi niyẹn ti a fi pinnu lati ṣa gbogbo ipa wa fun aṣeyọri idibo saa keji rẹ.

Leave a Reply