Idi ti aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa ko fi le wọle rara ni Naijiria – Adegboruwa

Faith Adebọla

Gbajugbaja ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Amofin agba Ẹbun Adegboruwa, ti ṣekilọ pe ọrọ ti ko ta, ti ko si le wọle rara ni erongba awọn ti wọn n sọ pe oludije funpo aarẹ ati igbakeji rẹ le jẹ ẹlẹsin kan naa, o ni ijakulẹ ati ifidirẹmi lo maa ṣẹlẹ si oludije eyikeyii to bo da a laṣa lati ṣeru ẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iweeroyin Punch laipẹ yii, Adegboruwa ni:
“Ọrọ ki ẹlẹsin Musulumi meji jẹ aarẹ ati igbakeji ko le wọle rara. O daa, ẹ jẹ ka wo ohun to maa ṣẹlẹ ka sọ pe ẹlẹsin Kristẹni meji lo fẹẹ dupo aarẹ ati igbakeji aarẹ. Iyẹn maa ri bakan pẹlu eto ta a n lo lọwọ ni Naijiria. Ẹsin meji lo lewaju ju lọ ni Naijiria lonii. Teeyan o ba jẹ Kristiẹni, aa jẹ Musulumi, bo tilẹ jẹ pe mo mọ pe awọn ẹlẹsin mi-in wa. Ta a ba fẹẹ sọrọ nipa gbigbe agbara kaakiri, o gbọdọ delẹ patapata. A ti gba pe ki agbara yipo lati Ariwa si Guusu, bẹẹ ni ọrọ ẹsin naa gbọdọ dọgba.
“Ẹgbẹ APC ti yan Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bii oludije aarẹ wọn, PDP si ti yan Alaaji Atiku Abubakar, Musulumi lawọn mejeeji, a o si le ko ipinnu ẹgbẹ wọn danu. Gbogbo nnkan ta a le ṣe ko ju ka ri i pe ipindọgba wa ninu ẹsin wọn, tori nnkan ta a reti ki wọn ṣe niyẹn, ohun ti ofin si sọ niyẹn. Labẹ isọri kẹẹẹdogun, abala keji, iwe ofin ilẹ wa, kedere lo sọ pe ko gbọdọ si ojuṣaaju ninu pinpin ipo ati agbara. Ni isọri kẹrinla, abala kẹta, iwe ofin kan naa, awọn baba wa sọ pe agbara ko gbọdọ fi sibi kan ju ibi kan lọ ni eyikeyii agbegbe orileede yii, ibaa jẹ ẹya tabi ẹsin.
“Ti a ba lọ latori Musulumi kan to ṣejọba fọdun mẹjọ, ti a tun bọ sọwọ Musulumi mi-in fọdun mẹjọ, ti Musulumi naa tun waa lọ yan Musulumi bii igbakeji aarẹ, ogun ẹsin ni wọn fẹẹ da silẹ yẹn, mi o si ro pe iyẹn daa fun orileede yii. Ọrọ yii o fi bẹẹ le lọdun 1993 nigba ti tawọn eeyan fi dibo fun MKO Abiọla ati Babagana Kingibe. Ṣugbọn ko si Boko Haram, ko sawọn ISWAP eeṣin-o-kọku. Ọrọ ti yatọ lasiko yii. Awọn eeyan n bẹru lati lọ ṣọọṣi, wọn n ji awọn adari ṣọọṣi gbe kaakiri bii eyi to waye nipinlẹ Kwara ati Ondo, wọn n yinbọn paayan bii eyi to ṣẹlẹ ni Ọwọ.
“Pẹlu gbogbo nnkan wọnyi, teeyan kan ba tun jade pe ẹlẹsin kan naa loun ati igbakeji oun, ẹni naa ko gba tawọn eeyan ro niyẹn, ero ti ko daa niyẹn si maa gbin sawọn eeyan lọkan.”

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: