Idibo 2023: ijọba fẹsun ibanilorukọjẹ kan ẹgbẹ oselu PDP, ni Kwara

Ibrahim Alagunmu

L’Ọjọ Iẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nijọba ipinlẹ Kwara, labẹ iejọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, fẹsun kan ẹgbẹ oelu alatako PDP, pe wọn ti bẹrẹ si ba ijọba to n bẹ lode lorukọjẹ ki wọn le pada sipo lọdun 2023.

 

Nigba ti olubanidamọran pataki si gomina lori ọrọ oelu nipinlẹ Kwara, n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin, lọjọ Iẹgun, o ni afẹfẹ ti fẹ, a ti ri fuf adiẹ, gbogbo igbesẹ ibanilorukọjẹ ti awọn ẹgbẹ alatako n gbe nipa irọ pipa, ie ayederu fidio, iroyin ofege, lati fi i awọn araalu lọna ki wọn le pada sipo ni ọdun 2023, nijọba ti mọ nipa rẹ, ti wọn si fẹ maa lo ori ayelujara lati fi gbogun ti ijọba.

 

 

O tẹsiwaju pe lara igbesẹ wọn ni eyi ti wọn sọ pe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun miliọnu to jẹ owo ijọba ibilẹ poora ninu iejọba Gomina AbdulRazaq, to si jẹ pe iwadii fihan pe irọ funfun balau ni. O rọ awọn araalu ki wọn ma gbọ ti ẹlẹgan, ki wọn jinna si awọn iroyin ofege tawọn ẹgbẹ oselu PDP gbe kiri.

Leave a Reply