Ajọ eleto idibo ti fun Ademọla Adeleke niwee-ẹri ‘mo yege’

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti fun gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, niwee-ẹri  ‘mo yege’ lati fi han pe oun lo jawe olubori idibo naa, ati pe ajọ naa fọwọ si i pe oun lo yege.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni wọn fun un niwee ẹri naa.

Kọmiṣanna ajọ eleto idibo to n ṣoju ipinlẹ Ọṣun, Ogun ati Ọyọ, Ọjọgbọn Kunle Ajayi, lo fi iwe-ẹri naa le oun ati igbakeji rẹ, Ọmọọba Kọla Adewusi, lọwọ ni olu ileeṣẹ naa to wa niluu Oṣogbo.

Tẹ o ba gbagbe, Sẹnetọ Adeleke lo wọle nibi eto idibo to waye nipinlẹ Ọsun ni Satide ọsẹ to kọja.

Leave a Reply