Ifẹtẹdo, nipinlẹ Ọṣun, ni Ọtẹdọla n ko ọpọlọpọ ori eeyan ti wọn ba lọwọ rẹ lọ tọwọ fi tẹ ẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn marun-un ni wọn ti wa lakolo ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori ẹsun tita ẹya ara eeyan ti wọn ji ninu ọgba itẹkuu kan to wa laduugbo Okudu, eyi to wa lagbegbe Ayeyẹmi, niluu Ondo.

Awọn afurasi maraarun, Ọpẹyẹmi Ọtẹdọla, Lanre Akinọla, Clement Adesanoye, Alowonle Kẹhinde ati Jubril Jimoh lọwọ awọn agbofinro tesan Funmbi Fagun tẹ nibi ọtọọtọ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ọtẹdọla ni wọn kọkọ ri mu lasiko to n gbe ọpọlọpọ ẹya ara oku to di sinu apo nla kan lọ si Ifẹtẹdo, nipinlẹ Ọsun, nibi to ti fẹẹ lọọ ta a fun babalawo to bẹ ẹ lọwẹ ni wọn mu un.

Asiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lo jẹwọ pe Ifẹtẹdo loun ti wa, ó ni awọn ẹgbọn oun kan lo ran oun lati lọọ gba awọn ẹya ara eeyan naa wa lọwọ Lanre Akintọla.

Bo ṣe gba ẹru ọhun tan ni gareeji Ifẹ to wa l’Ondo, lo di i m’ẹyin ọkada rẹ, to si mori le ọna Ifẹtẹdo, kọwọ awọn ọlọpaa too tẹ ẹ loju ọna.

Nigba ti wọn beere bọrọ ṣe jẹ lọwọ Akintọla, oun naa ko wulẹ ba wọn jiyan lori ẹsun ti wọn fi kan an, ó ni Adesanoye lo mọ bo ṣe wa awọn ẹya ara eeyan naa jade lawọn ibojì to wa ninu itẹ oku tí wọn ní ko maa mojuto laduugbo Okudu.

O fi kun un pe oun naa lo bẹ oun lọwẹ lati ba oun ṣọna bi awọn ẹya ara oku ọhun yoo ṣe de ọdọ Alowonle ati Jubril ti wọn n ṣiṣẹ babalawo niluu Ifẹtẹdo.

Akintọla ni oun ati Jubril ti n bọ lati ọjọ pipẹ, ati pe oun gan-an lo mu oun mọ Alowonle ti wọn jọ n ṣiṣẹ babalawo.

Awọn ẹya ara ti wọn ka mọ wọn lọwọ naa lo ni wọn fẹẹ fi ṣoogun fawọn ọmọ ‘Yahoo’ kan to bẹ wọn niṣẹ.

Awọn afurasi ọhun ni wọn ti fi ṣọwọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

 

Leave a Reply