Florence Babaṣọla
Adele alaga akọkọ fun ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii, Oloye Bisi Akande, ti sọ pe iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa to n lọ lọwọ ko bojumu rara, ko si yatọ si ifowoṣofo lasiko yii ti eto ọrọ-aje orileede yii ko rẹrin-in.
Lasiko ti awọn adari ẹgbẹ naa lorileede yii lọ sile Oloye Akande niluu Ila fun iforukọsilẹ baba naa lo ti woye pe ko boju mu ki ẹgbẹ oṣelu maa ṣe iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ laaarin ọdun mẹwaa sira wọn.
Baba Akande woye pe, “Wọn ki i ṣeto ikaniyan lai jẹ pe eyi to wa nilẹ pe ọdun mẹwaa, bẹẹ ni awọn oludibo ki i tun iforukọsilẹ ṣe ni gbogbo igba ti wọn ba fẹẹ dibo. Mo ri iforukọsilẹ tuntun ti wọn n ṣe lọwọ bayii ninu ẹgbẹ APC gẹgẹ bii eyi ti ko tọna, ti ko si sẹni to le sọ pe o bojumu.
“A ti ni akọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ to duro’re, to si jẹ pe awọn adari ti wọn lorukọ rere ni wọn ṣe kokaari rẹ kaakiri ibudo idibo to ju ẹgbẹrun lọna aadọfa lọ nigba naa.
“Owo to le ni biliọnu kan naira la na lori iforukọsilẹ naa lọdun 2014 ti eto ọrọ-aje orileede yii ṣi ṣe daadaa, to si jẹ pe owo ara wa la na nigba naa nigba ti ẹgbẹ APC ko ti i dejọba.
“Mo fẹ ki ẹ mọ pe idibo lati yan ẹni ti yoo gbapo lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari to n bọ lọna ni yoo sọ boya iforukọsilẹ ti a n ṣe lọwọ yii nitumọ tabi otubantẹ lasan ni. Ṣugbọn mo gbadura pe ka fi eto yii ni aṣeyọri to pọ”
Bakan naa ni Oloye Akande kilọ fun awọn ti wọn n sạkoso ẹgbẹ APC lọwọlọwọ lati ma ṣe joye ‘Akintọla taku’ sori ipo ti wọn wa gẹgẹ bi awọn alaṣẹ kan ṣe maa n ṣe lawọn orileede kan ti wọn ko ti i goke agba lagbaaye.