Igbakeji gomina Kwara tẹlẹ ti ku o!

Stephen Ajagbe, Ilorin

Igbakeji gomina Kwara tẹlẹ, to tun jẹ Aṣiwaju ilu Igosun, Oloye Simon Adedeji Ṣayọmi, ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaaadọrun-un.

Igbimọ awọn oloye laafin ọba ilu Igosun ati ẹgbẹ Itẹsiwaju ilu naa, Igosun Progressive Union, IPU, lo kede iku rẹ l’Ọjọbọ, Tọside, ninu atẹjade kan.

Aarẹ ẹgbẹ IPU, Oloye R.O Balogun, ṣapejuwe iku baba naa bii adanu nla fun ilu Igosun ati Kwara lapapọ.

Ṣayọmi lo dipo igbakeji mu lasiko iṣejọba Gomina Mohammed Lawal toun naa ti doloogbe, laarin ọdun 1999 si 2003.

Baba ọhun ni wọn lo fọwọ rọri ku nile rẹ ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: