Ẹjọ ni pasitọ yii fẹẹ ro, ọrọ lo si maa fi gbọ

Ẹ wo o, o daa ki eeyan naa daa. Bi eeyan ba daa, toun naa jẹ ọmọluabi, yoo ṣoro ki wahala kan too ba a. Nigba ti ọrọ yii ṣẹlẹ, mo fẹẹ le sọ pe lọjọ ti mo ti wa l’Oṣodi yẹn, tabi ti mo ti n ṣe ka-ta-ka-ra mi yii, inu ko bi mi to ti ọsẹ to lọ lọhun-un yẹn ri, nigba ti mo gbọ pe ọlọpaa mu ọmọ temi nitori pe o fun obinrin loyun, ti wọn waa purọ mọ ọn pe o ji ọmọ gbe ni. Ọmọ ti wọn n wi yii ti jade ileewe, o ti le lọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn, ṣe o waa jẹ ọmọ ti ko mọ ohun to n ṣe ni. Eyi to dun mi ju ni ti ohun ti wọn sọ pe o n bi ọkunrin pasitọ yẹn ninu.

Yoruba jọ ni wa o, Yoruba to gbede ara wọn, ki lo waa wa nibẹ ti a ko le yanju ẹ, afigba ti a ba n fẹdi ara wa sita fun aye ri. Ẹ ni ohun to n bii yin ninu ni pe Musulumi ni baba ẹ, Musulumi niya ẹ. Ṣe Musulumi ki i ṣe eeyan ni, abi awọn ti wọn ba n pe ara wọn ni pasitọ nikan leeyan Ọlọrun. Ohun to dun mi ju ninu ọrọ naa niyẹn. Ẹni to pe ara ẹ ni pasitọ, to mọ bi ọrọ ti ri, to mọ pe awọn ọmọ mejeeji n fẹ ara wọn, to waa lọ si ọdọ awọn ọlọpaa, to purọ mọ ọmọ mi pe niṣe lo ji ọmọ gbe. Bẹẹ o mọ Akin daadaa, o mọ pe ọmọ oun loyun fun un, sibẹ o parọ.

Ṣe keferi gbọdọ pa iru irọ buruku bẹẹ, ka maa ti i waa sọ ti ẹni to n pe ara ẹ ni eeyan Ọlọrun. Ṣugbọn Ọlọrun naa fi ajulọ han an o. Sẹki ṣalaye fun mi pe nigba ti wọn ti fẹẹ maa mu Akin lọ ni ọmọ to fun loyun ti sa jade, niyẹn ba waa ba oun, awọn jọ de tọlọpaa ni. O ni nigba ti awọn debẹ, ọdọ DPO loun ba Akin, nitori wọn ni wọn o gbọdọ ti i mọle. Bẹẹ pasitọ ti sanwo fun wọn pe ti wọn ba ti le ri i mu, nnkan ti ki wọn ṣaa kọkọ ba oun ṣe fun un ni ki wọn ti i mọle. O lo ji ọmọ oun gbe ni o. Ariwo to n pa niyẹn.

Ṣugbọn nigba ti wọn de teṣan, ti wọn fẹẹ maa ti Akin ni itikuti, bi DPO ati ọga mi-in ṣe n bọ lati ita niyẹn, n lo ba ri Akin, lo ba tẹju mọ ọn. Akin ni oun ko tiẹ mọ ọn daadaa, bẹẹ ọpọ igba lo ti lọ sibẹ to ti gbe nnkan fun wọn nigba to ṣi n ba mi ṣiṣẹ, awọn ọlọpaa naa dẹ maa n wa ọdọ wa, awọn ti wọn pawọ le DPO, ti wọn jẹ Yoruba, nitori ọmọ Edo ni wọn pe e, gayọ-gayọ kan bayi lo maa n sọ Yoruba. Ṣugbọn o bẹru mi, ohun to si fa a ni ọjọ ti ọga wọn wa si ọdọ mi, to ni oun fẹẹ ya teṣan awọn, ti mo waa ba a lọ. Ọjọ yẹn lo ti fi mi han an pe ọrẹ oun lemi.

Sẹki ni bo ṣe wọle to tẹju mọ Akin, o kan ju ọwọ firi lẹẹkan naa bii ẹni to ranti nnkan pataki ni, lo ba ni, ‘No bi Iya Biọla pikin bi dis?’ lawọn ọlọpaa ti wọn jọ n bọ ti wọn jẹ ọga ba ni bẹẹ ni. Lo ba leju mọ awọn ọlọpaa ti wọn n ti Akin kiri, lawọn yẹn ba sare fọmọ mi silẹ, lo ba tẹle e lọ si ọfiisi ẹ, nibẹ lo ti ṣalaye gbogbo ohun to ṣẹlẹ. Ọlọrun si kuku ṣe e, ọmọ ti wọn ni wọn ji gbe naa wa nibẹ funra ẹ, ni wọn ba beere pe ṣe wọn ji i gbe loootọ, lo ba n rẹrin-in, lo ni ki wọn ma da dadi lohun jare. DPO binu sawọn ọmọ ẹ, o mọ pe wọn ti gbowo lọwọ pasitọ ni.

Bi wọn ṣe fi ọmọ mi silẹ ko wale niyẹn o, wọn waa ni ko pada wa laaarọ ọjọ keji, pe pasitọ maa wa nibẹ, ki wọn le ba wọn yanju ẹ, pe ki oun naa mu baba tabi iya ẹ dani. Emi ni mo fẹẹ lọ, ṣugbọn inu to n bi mi ko jẹ, ni mo ba ni ki Alaaji lọ, oun ṣaa ni baba ọmọ, mo ni ki Safu ati Sẹki naa tẹle baba wọn, ti DPO tabi pasitọ ba si fẹẹ fi ọwọ ọla gba wọn loju, tabi to fẹẹ sọ pe oun jẹ kinni kan ni Oṣodi tabi l’Ekoo yii, ki Safu ṣaa ti bọ sẹyin tẹ mi laago. Ọrẹ mi ni mo maa pe, Usman, mo mọ pe ohun to maa foju awọn ọlọpaa yẹn ri, awọn naa ko jẹ ṣẹ iru ẹ mọ laye wọn.

Ohun ti mo ṣe tun fẹ ki Alaaji lọ bẹẹ ni pe oun naa ko fẹran ki awọn eeyan maa fi ọrọ ẹsin da wahala silẹ, mo dẹ mọ pe o maa halẹ mọ ati pasitọ ati ọlọpaa debii pe wọn o ni i ṣe iru ẹ mọ. Safu si royin fun mi, o ni nigba ti Alaaji foju kan pasitọ yẹn, niṣe lo dide mọ ọn, o fẹẹ la a nigbaaju. Wọn lo n beere lọwọ ẹ pe ki lo fi ẹsun ajinigbe kan ọmọ oun si, tabi ko mọ bi Naijiria ti le to ni, ki lo n fi ẹsun ọdaran kan ọmọ oun si. Lawọn ọlọpaa ba n bẹ ẹ. O ni ko le, ṣe pasitọ si ti ri ọmọ ẹ bayii abi ko ti i ri i. O loun ti ri i, ni Alaaji ba dide, ọrọ ṣaa dẹ ti tan.

Wọn ni lo ba sọ fun Akin pe ti oun ba tun ri i nile awọn araabi yẹn, tabi to ba jẹ ki ọmọ wọn wa sọdọ oun, ohun ti oun maa fi oju ẹ ri, ko ni i le royin ẹ tan fawọn ọmọ ẹ. Wọn ni ni pasitọ ba fo dide, lo ba ni oyun inu ẹ n kọ, ki Alaaji waa mọ bo ti fẹẹ ṣe e o. Wọn ni niṣe ni Alaaji mọ ọn loju, pe ṣebi oun ni ko fẹ ki ọmọ oun fẹ Musulumi, ẹn-ẹn ko lọọ yọ oyun inu ẹ jẹ, bi ko ba si le yọ ọ jẹ, ko gbe e sile ẹ ko maa tọju ẹ. Wọn ni nibẹ ni gbogbo agidi ti pasitọ n ṣe ti bọ, nitori niṣe ni iyawo ẹ bẹrẹ si i bẹ Alaaji, to n sọ pe awọn ko mọ rara pe ọmọ Iya Biọla l’Akin.

Nibẹ ni ọlọpaa yẹn naa ti wa n bẹ Alaaji, to ni ọrọ ẹsin ko yẹ ko fa ija bayii, paapaa laarin awa meji ti a gbọ ede ara wa. O kọju si pasitọ pe ṣe wọn ko fẹran ọmọ ti ọmọ wọn fẹẹ fẹ ni, ẹni to ni iṣẹ lọwọ, to ti kawe jade, to si tun ti ile to daa to bayii wa, kin ni wọn tun wa n fẹ. O ni ọrọ owo tabi pe ọmọ ti ile rere wa kọ, ọrọ pe wọn ki i ṣe ẹlẹsin kan naa bii tawọn ni. Wọn ni nibẹ ni iyawo ẹ ti binu, to n sọ fun gbogbo awọn to jokoo pe ile Musulumi ni pasitọ ti wa, Musulumi ni iya ẹ ati baba ẹ, oun kan ya si ọna ṣọọṣi nigba to dagba ni. Wọn ni nigba ti Alaaji gbọ bẹẹ, bo ṣe fibinu dide niyẹn, lo ba ni ki DPO ma binu. Ati Akin ati Safu ati Sẹki, o ni ki wọn niṣo nile.

A ṣaa ti dupẹ pe ọrọ ti pari bayii, nitori awọn agbaagba Oṣodi ti da si i. Awọn ọrẹ mi naa ti waa bẹ mi, koda iya iyawo gan-an ti wa. Emi naa ti lọọ ba a nile, iyẹn iya iyawo ni o, n ko ti i ri pasitọ nitori inu mi ṣẹṣẹ n rọlẹ si i diẹdiẹ ni. Awọn Sẹki ati Safu ṣaa ti bẹrẹ ipalẹmọ igbeyawo, emi si ti sọ fun wọn pe gbogbo ọrọ to ba le la ariwo lọ lasiko Korona yii, emi o fẹ ẹ o. Wọn tiẹ ni pasitọ naa ti sọ bẹẹ, wọn lo loun o le ko awọn agbalagba ijọ wa sibi iyawo ọmọ oun to fẹ Musulumi. Mo dẹ ti sọ fun wọn pe ẹjọ lo fẹẹ ro, ọrọ lo si maa fi gbọ!

Leave a Reply