Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ti gbe igbimọ ipolongo ibo ijọba ibilẹ kalẹ. Igbakeji gomina ipinlẹ yii, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, ni wọn yan gẹgẹ bii olori igbimọ ti yoo ri si ipolongo ibo ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2021 yii.
Iṣẹ to wa niwaju awọn igbimọ ipolongo naa, SCC (State Campaign Committee) ni lati ri si bi gbogbo ipolongo ibo fẹgbẹ APC yoo ṣe lọ, ki wọn si ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn igbimọ ipolongo kọọkan.
Akọwe to n kede fẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Tunde Ọladunjoye, lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an, oṣu keje yii, l’Abẹokuta, iyẹn ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn akọroyin.
Atẹjade naa ṣalaye iṣẹ ti igbimọ olupolongo yii ni lati ṣe, wọn ni gbogbo ipolongo pata fẹgbẹ APC, titi de ori alakalẹ atẹ bi eto kọọkan yoo ṣe waye ati bi wọn yoo ṣe rin ni awọn ibi gbogbo ti wọn yoo gbe ikede ibo ijọba ibilẹ yii de ni wọn yoo ri si.
Wọn fi kun un pe wọn yoo ṣafihan awọn akanṣe iṣe ti Gomina Dapọ Abiọdun yoo ba wọn ṣi lasiko ti wọn ba n polongo ibo kiri ijọba ibilẹ ogun (20) to wa nipinlẹ Ogun.
Awọn igbimọ yii ni yoo ri si awọn nnkan eelo ti ẹgbẹ yoo lo fun ipolongo, wọn yoo gbe eto iṣuna owo wọn kalẹ, wọn yoo si wa ọna ti owo le gba wọle lati ṣaṣeyọri nipa eto ti wọn yan wọn fun ọhun.
Awọn ti wọn dangajia lẹka ti wọn di mu lo wa ninu igbimọ SCC yii, diẹ ninu wọn wa lati ẹka to n ṣiṣẹ fun APC nipinlẹ yii (APC State Working Committee), awọn mi-in jẹ ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin, awọn oludamọran pataki atawọn amugbalẹgbẹẹ pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun.
Awọn ọmọ igbimọ naa ree bi wọn ṣe to orukọ wọn lẹsẹẹsẹ.
Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele- Alaga, Ọnarebu Yẹmi Adelani, Ọnarebu Afọlabi Afuapẹ. Ọnarebu Tunji Akinosi, Alaaji Waheed Oduṣile, Ọnarebu Biyi Adelẹyẹ, Ọnarebu Babatunde Ọlaotan,Ọnarebu Funmi Ẹfuwapẹ, Ọnarebu Tunde Ọladunjoye, Yetunde Adesanya, Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ, Ọnarebu Deji Kalẹjaye, Ọnarebu Ifẹkayọde Akinbọde, Ọnarebu Remmy Hassan, Ọnarebu Atinukẹ Bello, Ọnarebu Kọla Salakọ,Ọnarebu Taiwo Oludọtun,Ọnarebu Tolu Bankọle, Ọnarebu Fẹmi Akinwumi, Kọmureedi Azeez Adeyẹmi,Kọmureedi Ọlamide Lawal, Ọnarebu Koye Ijaduoye ati Ọnarebu Hadi Sani.
Awọn yooku ni:Ọnarebu Monday Chukwudi, Ọmọwe Emmanuel Taiwo, Ọnarebu Nikẹ Ọṣọba, Ọnarebu Oyindamọla Adeshina-Oyelẹsẹ, Ọnarebu Fẹmi Ilọri, Ọnarebu Goke Awọṣọ, Ọnarebu Kunle Ṣobukọnla, Rep Adewunmi Ọnanuga, Rep Kọlapọ K.Ọṣunsanyo, Rep Ibrahim Isiaka, Rep Jimọh Ojugbelẹ, Rep Jimọh Ọlaifa, Ọnarebu Adeyẹmi Harrison, Bolu Owotọmọ, Ọnarebu Daisi Ẹlẹmide, Ọnarebu Demọla Balogun ati Ọnarebu Adeshina Popoọla.