Igbakeji ọga ọlọpaa tuntun fun Ẹkun kọkanla bẹrẹ iṣẹ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹkun kọkanla fun ileeṣẹ ọlọpaa (Zone 11), ti ni ọga tuntun bayii, AIG Sholla David fdc, Psc(+).

Ẹkun kọkanla lo n ṣakoso ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, ọọfiisi wọn si wa lagbegbe Abere, niluu Oṣogbo.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ẹkun naa, SP Ayẹni Benjamen, fi ṣọwọ si ALAROYE lo ti ṣalaye pe AIG Sholla ti ṣiṣẹ lawọn ipinlẹ bii Kano, Lagos, Delta, Gombe, Kebbi, Ọyọ, Ogun, Sokoto, Abia ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Kọmisanna ọlọpaa ni ọkunrin naa nipinlẹ Bayelsa ko too di igbakeji ọga agba patapata ninu oṣu kẹta, ọdun 2019, nigba naa ni wọn gbe e lọ si ile-ẹkọ awọn ọlọpaa (Police Staff College) to wa niluu Jos gẹgẹ bii adari nibẹ.

One thought on “Igbakeji ọga ọlọpaa tuntun fun Ẹkun kọkanla bẹrẹ iṣẹ l’Oṣogbo

Leave a Reply