Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lẹyin ọsẹ meji ti awọn ajinigbe gbe ọmọ ati iya kan gbe ni agbegbe Ajebandele, ni Ado-Ekiti, awọn ajinigbe ti tun ji ọkunrin kan ati obinrin ti wọn n mura igbeyawo niluu Ilasa-Ekiti.
Gẹgẹ bi awọn tọrọ naa ṣoju wọn ṣe sọ, opopona to lọ lati ilu Ilasa Ekiti si Ayebode-Ekiti, ni wọn ti ji awọn tọkọ-taya naa gbe.
Ilu Ado-Ekiti, nibi ti wọn ti lọọ ra oun eelo igbeyawo wọn ti wọn fẹẹ ṣe ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to n bọ, ni wọn ti n bọ ki wọn too ko sọwọ awọn ajinigbe.
Wọn ni ibi kan ti ko dara loju popo naa ni awọn agbebọn yii ti jade lati inu igbo, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn soke, ti wọn si ko ọkọ ati iyawo yii wọnu igbo lọ.
ALAROYE gbọ pe lẹyin wakati marun-un ti wọn ti ji ọkọ ati iyawo yii gbe ni wọn pe awọn mọlẹbi wọn, ti wọn si beere miliọnu marun-un naira ki wọn too le gba iyọnda.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu sọ pe awọn ọlọpaa ti mu eeyan mẹta lori iṣẹlẹ naa.
O ṣalaye pe awọn mẹta naa ti wa ni atimọle, ti iwadii si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa. O fi kun un pe awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wa ninu igbo ni agbegbe naa, ti wọn si n sa gbogbo ipa wọn lati gba ọkọ ati iyawo naa silẹ.