Ija dopin! Igbakeji gomina Ọṣun ra mọto ṣọja tawọn janduku bajẹ n’Ikire pada

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun to tun jẹ ọmọ bibi ilu Ikire, Ogbeni Benedict Olugboyega Alabi, ti wa gbogbo ọna lati jẹ ki alaaafia pada jọba niluu abinibi rẹ o. O tira ọkọ tuntun pada fawọn ṣọja ti wọn wa fun ipẹtu-si-aawọ lasiko wahala to bẹ silẹ n’Ikire laipẹ yii, nibi tawọn janduku ti sọna si mọto awọn ṣọja naa, ti mọto ọhun si jona kọja sisọ.

Ṣaaju lawọn ṣọja naa ti funra wọn ri ibọn atawọn ọta wọn tawọn janduku  naa ko lọ gba pada. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni Igbakeji gomina ra mọto Hilux tuntun miiran fawọn ṣọja yii, wọn si ti fi ilu Ikire silẹ lẹsẹkẹsẹ, lẹyin ti wọn gba mọto wọn.

Alaafia ti pada jọba n’Ikire bayii, onikaluku si ti n ba iṣẹ rẹ lọ ni Pẹrẹu.

Leave a Reply