Adewale Adeoye
Ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn tawọn ọlọpaa agbegbe Ajegunlẹ, nipinlẹ Eko, ko fẹẹ darukọ nitori ti iwadi ṣi n lọ lọwọ nipa rẹ ti ku sileewosan alaadani kan ti wọn gbe e lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii. Bẹẹ lawọn meji ti wọn fara pa yannayanna lasiko ija agba meji to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun n gba itọju lọwọ nileewosan kan.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun adugbo Nasamu, ati ti adugbo Iyalode, ni Ajegunlẹ, kọju ija sira wọn, ‘mo ju ọ, mi o ki i ṣe ẹgbẹ rẹ’ lo dija silẹ laarin wọn, kawọn olugbe agbegbe naa si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, idarudapọ nla ti bẹ silẹ ni gbogbo agbegbe naa, ija naa le debii pe oniruuru nnkan ija oloro ni wọn fi n bara wọn ja lọjọ yii. Wọn ṣe ọpọ eeyan leṣe gidi, bẹẹ ni dukia awọn araalu kan ba iṣẹlẹ ọhun lọ lasiko ija naa.
ALAROYE gbọ pe ọpọ awọn mọto akero ti wọn ba ni ikorita Boundary Roundabouts, niluu naa ni wọn bajẹ kọja atunṣe lasiko ija yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe loju-ẹsẹ tawọn ti gba ipe pajawiri nipa iṣẹle ọhun lawọn ti lọọ pẹtu sija naa, tawọn si fọwọ ofin mu awọn kan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan ni wọn n bara wọn ja lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ija naa le debii pe ọpọ dukia awọn araalu ti wọn ko mọwọ-mẹsẹ ni wọn bajẹ, lẹyin tawọn araalu pe wa lori foonu la lọọ le gbogbo wọn danu, a fọwọ ofin mu awọn kan, nigba tawọn yooku wọn sa lọ.
Lara awọn ta a mu ni ọgbẹni kan ta a gbagbọ pe ọkan lara wọn ni, ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn ni, o fara pa yannayanna lasiko laṣiigbo naa, a gbe e lọ sileewosan aladaani kan to wa lagbegbe ọhun, ṣugbọn ko pẹ ta a gbe e debẹ to fi ku. Awọn mi-in ta a mu ti wọn tun fara pa wa nileewosan naa bayii, wọn n gba itọju lọwọ. A n wa awọn yooku wọn, lẹyin ta a ba mu wọn la maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.