Ijakulẹ ba aadọjọ ninu awọn to fẹẹ lọ si Mẹka, ajọ alalaaji lo fọ wọn jẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan aadọjọ (150) ninu awọn to fẹẹ rin irin-ajo mimọ lọ si Makkah ati Medina, lorile-ede Saudi Arabia, lọdun 2022 yii, ni ko ni i le lọ lọdun yii mọ.
Eyi ko ṣẹyin bi ijọba orile-ede Saudi ṣe kọ lati fun awọn arinrin-ajo naa ni iwe irinna lati ṣiṣẹ Oluwa ti wọn fẹẹ lọọ ṣe.

Alaga igbimọ alamoojuto irinajo mimọ Haaji nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Sayed Malik, lo fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan.

Sayed sọ pe jija ti wọn ja awọn alalaaji silẹ yii tun wa ni ibamu pẹlu eto ti awọn National Hajj Commission of Nigeria (NAHCON), iyẹn igbimọ to n ṣakoso irinajo haaj lorileede yii ṣe lati ri i pe awọn ti yoo rinrin-ajo mimọ lọdun yii ko pọ ju bo ṣe yẹ lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ẹgbẹrun mẹtalelogoji (43,000) lapapọ iye ọmọ Naijiria ti ajọ NAHCON sọ pe wọn yoo lọọ ṣiṣẹ Hajj lọdun yii, okoolelẹgbẹta o le mẹsan-an (629) ninu ẹ ni wọn si yọnda fun ipinlẹ Ọyọ, bẹẹ awọn to ti forukọ silẹ nipinlẹ yii ti le lẹgbẹrun kan.

“Eyi lo mu wa bẹ ajọ NAHCON lati fun wa lanfaani aadọjọ eeyan si i, wọn si gba fun wa. Iyẹn lo jẹ ki apapọ iye eeyan ta a maa ko lọ si Mẹka lọdun yii nipinlẹ Ọyọ jẹ ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrin o din ẹyọ kan (779).

“Eto ti a n ṣe naa ni pe eeyan ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrin o din ẹyọ kan (779) la maa ko rinrin-ajo mimọ lọ si Mẹka lọdun yii, ni ibamu pẹlu ajọsọ wa pẹlu ajọ NAHCON, ṣugbọn nigba ti asiko to lati ko awọn ero wa to ṣẹku lọ si Saudi, lajọ NAHCON tun din iye wa ku pada si okoolelẹgbẹta o le mẹsan-an (629)”.

Ta o ba gbagbe, ijọba orileede Saudi ko fun awọn eeyan lanfaani lati ṣiṣẹ haaji lọdun 2022 ati 2021, nitori ajakalẹ arun Korona. Eyi lo mu ki awọn to fẹẹ ṣiṣẹ Ọlọrun naa pọ lọdun yii kọja bo ṣe yẹ.

Alaga igbimọ alalaaji ipinlẹ Ọyọ ti waa rọ awọn to ba ṣi fẹẹ lo owo wọn fun irinajọ naa lọdun 2023 lati fọkan wọn balẹ. O ni awọn gan-an nigbimọ oun yoo ri i pe wọn kọkọ gbera lọ si Mẹka lọdun to n bọ.

Leave a Reply