Ijamba ina ba dukia rẹpẹtẹ jẹ lọja Ilupeju, niluu Ọyọ 

 Ọlawale Ajao, Ibadan

 Dukia miliọnu rẹpẹtẹ Naira lo ṣegbe sinu ijamba ina to waye lọja Ajegunlẹ, niluu Ọyọ.

 Bi ọpọlọpọ ijamba ina ṣe maa n saaba waye naa lo ṣe ṣẹlẹ ninu ọja to wa ni Ajegunlẹ, niluu Ọyọ, ṣe lawọn ara ọja naa deede ba ina to n jo ṣọọbu wọn laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun (23), oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

 kan ninu awọn ontaja nibẹ sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe ọkan ninu awọn to n yan gaari ninu ọja yii ni ko pa ina tan daadaa lẹyin to yan gaari tan lọjọ naa, ti ina naa fi ran mọ awọn nnkan mi-in, to si di ohun to ṣokunfa ijamba ina to fi ọpọlọpọ dukia ṣofo yii.

 ALAROYE gbọ pe abala isọ gaari ninu ọja

to wa lọna Ọyọ, siluu Ogbomọṣọ yii, lo fara gba ju lọ ninu ijamba ọhun.

 Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Akinyinka Akinymiju, sọ pe bi awọn oṣiṣẹ awọn ṣe tete de sibi iṣẹlẹ naa ni ko jẹ ki ijamba ina ọhun pọ kọja ibi to de duro ti awn fi pa a.

 O waa gba gbogbo eeyan niyanjanju lati maa pa gbogbo ina ile ati ti ibi iṣẹ daadaa ni kete ti wọn ba lo awọn ina ọhun tan. O ni eyi lọna pataki to daa ju lọ lati maa dena iṣẹlẹ ijamba ina, paapaa lasiko ẹẹrun ta a wa yii, ti iṣẹlẹ ina saaba maa n waye ju lọ.

Leave a Reply