Ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn agbebọn to yinbọn pa Dokita ni Kwara lọjọsi  

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin 

 Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, ni afurasi kan, Mohammadu Aminu, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn, wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o wa lara awọn agbebọn to yinbọn pa Dokita oniṣegun oyinbo kan, Adefikayọ James Alabi, niluu Kàńńbí, nijọba ibilẹ Móòrò, nipinlẹ Kwara, ti wọn si tun ji ọmọ ẹ obinrin Christiana Alabi, gbe lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun to kọja. 

 Tẹ o ba gbagbe, nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2023 to kọja yii, niṣẹlẹ buruku yii waye, nigba ti afurasi ọhun, Mohammed Aminu, atawọn ẹruuku yooku rẹ tawọn ọlọpaa i n wa ya bo ilu Kàńńbí, ti wọn si gba ile Dokita Adefikayọ lọ taara, wọn bẹrẹ si rọjo ibọn, lasiko naa ni wọn yinbọn pa Dokita yii, wọn si ji ọmọ rẹ obinrin kan sa lọ.

 L’Ọjọ keji iṣẹlẹ naa ni wọn fi nọmba ibaniṣọrọ 07054301672 pe mọlẹbi, ti wọn si n beere fun aadọta miliọnu Naira gẹgẹ bii owo tusilẹ. 

 Awọn Fijilante ya bo igbo kan to wa lagbegbe Babadudu, nijọba ibilẹ Móòrò, nibi ti wọn ti doju ibọn kọra pẹlu awọn ajinigbe ọhun, nibẹ ni wọn si ti ri Christiana doola lai sanwo, ṣugbọn awọn ajinigbe naa pa ọkan lara fijilante ti wọn pe orukọ rẹ ni Jamiu, ibọn ba ọkan lara awọn ajinigbe naa, iyẹn Mohammed, to si fara pa yannayanna. 

 Ni bayii, ara Mohammed Aminu ti ya, to si ti jẹwọ pe loootọ loun wa lara awọn ajinigbe to n yọ awọn eeyan Kàńńbí, Olóooru, Shàó ati Bodè-Sáadú, nijọba ibilẹ Móòrò, lẹnu. O ni ọmọ bibi ilu Sokoto, nipinlẹ Sokoto, loun, Fulani darandaran si ni oun tẹlẹ koun too darapọ mọ iṣẹ ajinigbe. Awọn ọlọpaa ti ni ki afurasi ọdaran yii maa lọọ kawọ pọnyin rojọ niwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan nluu Ilọrin.

Leave a Reply