Ba a ṣe yọ Oluọmọ ko kan gomina, eyi nidi ta a fi yọ ọ – Ṣonẹyẹ

Faith Adebọla

Gbogbo eto ọhun fẹrẹ ma ju laarin ka diju ka la a lọ, ti wọn fi gba ọpa aṣẹ danu lọwọ olori awọn aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, ti wọn si yọ ọ nipo olori ileegbimọ aṣofin naa. Wọn lawọn ẹṣun ti Oluọmọ jẹbi rẹ pọ, awọn ẹsun naa si n bi awọn ẹlẹgbẹ rẹ ninu, eyi lo mu ki wọn yọ ọ bii ẹni yọ jiga lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2024 yii, ti wọn si yan ẹlomi-in rọpo rẹ lẹyẹ-o-sọka.

Ọpọ awuyewuye lo ti dide lori yiyọ ti wọn yọ olori aṣofin naa, bawọn kan ṣe n sọ pe ejo ọrọ rẹ lọwọ ninu, ti wọn fẹsun kan Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, pe oun ni onilu to wa nisalẹ odo to n lulu fun iromi awọn aṣofin ọhun lati jo, ti wọn lohun ti Dapọ fọn si feere awọn aṣofin ni awọn naa fọn jade lọjọ Tusidee yẹn, bẹẹ lawọn kan n sọ pe afago-kẹyin-aparo ni Oluọmọ funra ẹ, wọn lohun toju rẹ wa loju rẹ ri yii, oun lo huwa aitọ ti wọn fi yẹ aga nidii ẹ.

Amọ Abẹnugan tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọnarebu Daisi Olumide, ati ẹlẹgbẹ rẹ kan, Ọnarebu Damilọla Ṣonẹyẹ, ti ni bi ọrọ papa ko ṣe kan ẹja, bẹẹ lọrọ iyọnipo Oluọmọ ko ṣe kan gomina ipinlẹ Ogun.

Ẹlẹmide, to ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ọdẹda sọrọ lẹyin ti wọn yan an sipo olori awọn aṣofin naa, o ni, “awọn aṣofin to n tẹle ofin ni gbogbo wa yii. A fẹ ki gbogbo aye mọ pe omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọn ọ. Aṣofin mejidinlogun lo buwọ lu u pe ki n di olori awọn. “A fẹ kẹyin araalu lọọ fọkan balẹ, gbogbo aṣẹ ile aṣofin yii lo wa nikaawọ wa, iṣakoso tuntun yii maa ti gomina wa lẹyin.

“Gomina ko mọ ohunkohun lori yiyọ ti wọn yọ Oluọmọ o, ko kan an rara,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Bakan naa ni ọrọ ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ọbafẹmi Owode, Ọnarebu Damilọla Ṣonẹyẹ, sọ. O ni, “Idi ta a fi yọ olori wa tẹlẹ ni pe o hu awọn iwa to buru jai, awọn iwa bii agidi, tinu-mi-ni-ma-a-ṣe, igberaga, aiṣootọ, ati pe o jẹ adari ti muṣemuṣe rẹ ko da muṣemuṣe. O tun ṣe awọn owo kan baṣubaṣu, bẹẹ lo maa n fori awọn aṣofin gba ara wọn.”

Ẹ oo ranti pe awọn aṣofin mejidinlogun ni wọn tọwọ bọwe pe awọn fara mọ igbesẹ yiyọ Ọlakunle Oluọmọ nipo olori ile lọjọ Tusidee ọhun, ki wọn too yan Ẹlẹmide rọpo rẹ.

Igbakeji olori ile, Ọnarebu Bọlanle Ajayi, lo dari eto ile naa, Ọnarebu Adegoke Adeyanju lati ẹkun idibo Ariwa Yewa kin-in-ni lo kọkọ mu aba pe ki wọn yọ Oluọmọ nipo wa, ti Ọnarebu Ademọla Adeniran lati  ẹkun idibo Ṣagamu keji si ki in lẹyin.

ALAROYE gbọ pe Ọnarebu Adeniran lo gbe ọpa aṣẹ ile naa dani, oun at’ọpa naa ni wọn jọ de sileegbimọ aṣofin lọjọ ọhun, tawọn aṣofin yooku si n tẹle e bọ.

Wọn ni yatọ si ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan Oluọmọ, iwa agidi ati ganran-ganran rẹ to legba kan si i, ati iwa fifori eku gba tẹyẹ laarin awọn ọmọ ileegbimọ naa wa lara ohun to bi awọn ẹlẹgbẹ rẹ ninu si i.

Leave a Reply