Faith Adebọla, Eko
“Nnkan ẹgbin, iwa radarada to riiyan lara ni, eewọ si ni pẹlu. Gbogbo igba ni mo n sọrọ ta ko iru aṣa palapala bẹẹ, koda ki n too di gbajumọ ni mo ti n sọ ọ. Ijiya to gbopọn gbọdọ wa fun ẹnikẹni to ba huwa aitọ, ki nnkan le lọ daadaa. Tabi kẹ, ẹnikẹni ti ajere iru aṣa buruku bẹẹ ba ṣi mọ lori, ki wọn fimu onitọhun danrin, ki awọn yooku le dẹkun iṣekuṣe”.
Eyi lawọn ọrọ to n jade lẹnu gbajugbaja adẹrin-in poṣonu oṣere tiata ilẹ wa nni, Debọ Adedayọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Mista Macaroni, nigba to n sọrọ ta ko ẹsun ti wọn fi kan awọn oṣere tiata kan ti wọn maa n fi ibalopọ lọ oṣere ẹlẹgbẹ wọn ki wọn too le jẹ ki wọn kopa ninu fiimu.
Debọ ni gbogbo igba loun maa n sọrọ lodi si aṣa buruku naa lori ikanni abẹyẹfo (tuita) oun, ninu awọn ọrọ toun n ju sita, oun si ta ko iwa naa loju aye pẹlu, tori iwa to n rẹ ni walẹ ni, iwa ailọwọ, to fi bawọn eeyan ṣe ya ika ati alailaaanu ẹda han ni.
“Bi ẹnikan ṣe to si, to si jafafa to, lo yẹ ko pinnu boya wọn maa fun un ni ipa lati ko ninu fiimu, ati bi tọhun ṣe le kopa ti wọn ba fun un yanju si. Eeyan meloo lẹnikan fẹẹ ba sun gan-an?
“Ki i ṣe idi iṣẹ tiata lawọn aṣa buruku bẹẹ wa o, o wa kaakiri ni, ẹnikan aa ni ko o lọọ mowo wa koun too ba ẹ waṣẹ tabi fun ẹ niṣẹ, ṣe to ba lowo lọwọ, aa tun maa wa’ṣẹ ni?
“Fun ẹyin ọjẹwẹwẹ onitiata to ṣẹṣẹ n goke, imọran mi fun yin ni pe kẹ ẹ wo Mista Macaroni daadaa, ẹ lọọ wo itan igbesi aye mi ati irinajo mi, ẹẹkan naa kọ ni aṣeyọri maa n de, diẹdiẹ ni. Mo ti n kopa ninu ere lati nnkan bii ọdun 2010, ṣugbọn pẹlu oore-ọfẹ Ọlọrun, 2019 lawọn eeyan too bẹrẹ si i mọ mi, tori ẹ, ẹ ma ṣe kanju, asiko ni gbogbo nnkan fun ẹda, ẹ maa ba irinajo yin lọ, aluyọ maa ṣẹlẹ, tẹ ẹ ba ṣiṣẹ fun un.
“Ẹ ma ṣe ro pe o digba tẹ ẹ ba ta ara yin lọpọ tabi kẹ ẹ lọwọ ninu iwa aitọ kẹ ẹ too le goke, irọ ni, iṣẹ aṣekara ati adura, pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun ko fun yin ni oore-ọfẹ lo le mu yin goke.
“Mo rọ ẹyin tẹ ẹ lẹbun ti wọn n fi ibalopọ lọ, ẹ jẹ oloootọ si ara yin, ẹ si duro lori ipinnu yin, ki i ṣe kẹ ẹ sọrọ kan lonii, kẹ ẹ tun sọ eyi to yatọ lọla o.”