Erin wo! Asẹyin ilu Isẹyin waja

Ọlawale Ajao, Ibadan

Asẹyin tilu Iṣẹyin, Ọba Abdul Ganiy Adekunle Salawudeen (Ajinẹsẹ Keji), ti waja.

Iroyin to tẹ akọroyin wa lọwọ lati aafin Asẹyin fidi ẹ mulẹ pe lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2022. Ọba nla yii, to jẹ igbakeji alaga igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ Ọyọ dara pọ mọ awọn baba nla ẹ.

Ipapoda ori ade yii lẹlẹẹkeje ọba ti yoo waja laarin oṣu mẹjọ sasiko yii nipinlẹ Ọyọ.

Awọn ọba to ti kọkọ waja laarin asiko naa ni Ajoriwin tilu Igbẹti, Ṣọun ti Ogbomọṣọ, Olubadan tilẹ Ibadan, Aṣigangan ti Igangan, Alaafin Ọyọ ati Onijẹru ti Ijẹru, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fi Olubadan tuntun jẹ ni nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o to bii ọjọ meloo kan ti ojojo ti n ṣogun Ọba Salawudeen, lọjọ Kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2022 yii, niroyin ti kọkọ gba ilu kan pe ọba naa ti waja, ṣugbọn ti ọrọ ko pada ri bẹẹ mọ, ko too di pe iku pada ka a mọ ori apere, to si ṣe bẹẹ jẹ ipe awọn baba nla ẹ.

Ọsibitu UCH, niluu Ibadan to ti wa lati bii oṣu diẹ ni wọn ni ọba alaye naa dakẹ si.

Leave a Reply