Ọwọ ọlọpaa tẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun meje ni Omuo-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹka to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun ti ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ wọn ti tẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun meje ni Omuo-Ekiti, nijọba ibilẹ Ariwa Ekiti, nipinlẹ Ekiti.

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ni wọn sọ pe wọn mu pẹlu atilẹyin ajọ fijilante to wa nijọba ibilẹ naa.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣe sọ, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti wọn jẹ meje ni ọwọ awọn tẹ nileeṣẹ kan ti wọn ti n fọ okuta to wa niluu naa, nibi ti wọn ti n ṣe ipade wọn, ti wọn tun n ṣe ayẹyẹ gbigba ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle sinu ẹgbẹ wọn.

Orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n: Gbenga Oluwatobi, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Akinọla Ademọla, ọdun mejilelogun, Rotimi Tolulọpẹ, ẹni ọdun marunlelogoji, Samuel Ṣẹsan, ọdun mejilelogun, Abiọdun Adeleke ọdun mejilelogiji, Ọlagunju Temitọpẹ ọdun mọkanlelogun ati Adekunle Oluwaṣeun ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọdaran naa ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ni wọn, ibi ti wọn ti n ṣe ipade wọn ti wọn maa n ṣe lọsọọsẹ ni agbegbe naa, ti wọn si tun n gba ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle ni awọn ọlọpaa ti ri wọn  mu.

Abutu ṣalaye pe igbo tutu to pọ lọpọlọpọ ni wọn gba lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa, bakan naa ni wọn tun gba iwe nla kan to ni akọsilẹ orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ninu lọwọ wọn.

Lara awọn orukọ ati ipo ti wọn ba ninu iwe naa ni, Coordinator, N.G1 titi de N.G5, Flight Commander 1 ati Flight Commander 7, Eagle 1 titi de Eagle 8, Government, Mopol 33, ati awọn orukọ ati ipo miran.”

Abutu fi kun un pe awọn ọdaran naa yoo foju ba ile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ wọn. Bakan naa lo sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lati mu awọn yooku ti wọn sa lọ mọ ọlọpaa lọwọ lakooko ti wọn ka wọn mọ ibuba wọn naa.

Leave a Reply