Ijọba apapọ ni lati ṣe pẹlẹpẹlẹ lori ọrọ Sunday Igboho- Ladọja

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi ijọba orileede Benin ṣe mu ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho), ti wọn si n mura lati fa a le ijọba Naijiria lọwọ funya jẹ, gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Senitolọ Rashidi Adewọlu Ladọja, ti gba ijọba apapọ nimọran lati tẹ ẹ jẹẹjẹ lori ọrọ ọkunrin ajijagbara naa.

Lasiko to n gba awọn oniroyin lalejo fun ọdun Iléyá lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo sọrọ naa nile ẹ to wa laduugbo Bodija, n’Ibadan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Aiṣedeede ijọba apapọ naa lo sọ ọ di olokiki, paapaa lori ọrọ Igangan.  Gbobo eeyan lo ti sọ ọ, Alaafin paapaa sọ ọ, pe nigba ti wọn ba mu ẹnikan fun iwa ọdaran, paapaa bi ẹni naa ba jẹ Fulani, niṣe laṣẹ maa wa latoke pe ki wọn fi onitọhun silẹ.

“Wọn pa ọpọ eeyan lagbegbe Ibarapa. Aarin ọsẹ kan sira wọn ni wọn pa Dokita Aborode ati obinrin kan to ni ileepo lagbegbe yẹn. Bẹẹ ni wọn ṣe pa ogunlọgọ eeyan, ṣugbọn ti wọn ko ri ẹnikẹni mu ninu awọn to hu awọn iwa ọdaran wọnyẹn.

“Eyi ni Sunday Igboho ta ko pe ko yẹ ko maa ri bẹẹ. Ohun to sọ ọ dolokiki niyẹn.

“Ijọba apapọ ni lati ṣe pẹlẹpẹlẹ lori ọrọ yii nitori ti wọn ba mu Sunday Igboho, aimọye iru eeyan bii tiẹ lo wa nigboro kaakiri.

“Ko sẹni to mọ nnkan to maa ṣẹlẹ si Igboho ni awọn ijọba ilẹ Benin ba fa a le ijọba orileede yii lọwọ. Gẹgẹ bi Nnamdi Kanu ṣe jẹ olori fawọn kan nilẹ Ibo, bẹẹ ni Sunday Igboho naa ti di aṣáájú fawọn kan naa bayii.

Bi Kanu ṣe wa yẹn, ba a fẹ, ba a kọ, o ti di olori awọn kan. Gẹgẹ bẹẹ nIgboho naa ti ṣe di olori fawọn kan bayii. Ti ijọba ko ba ṣe e jẹẹjẹ, o le di nnkan ti awọn ajijagbara bii Kanu ati Igboho fi maa pọ si i lorileede yii dide.

“Bi wọn ṣe n dariji awọn Boko Haram, ki wọn dariji Kanu ati Igboho naa. Bii ẹgbẹrun kan awọn ikọ Boko Haram (ìkọ to n fẹmi awọn eeyan ṣofo nipinlẹ Borno)  to wa latimọle kan ṣaa nijọba apapọ tu silẹ ti wọn yọnda fun ijọba Borno lọsẹ to koja. Ohun to ba mu ki ijọba maa dariji awọn Boko Haram to n fẹmi awọn eeyan ṣofo, o yẹ ki wọn le fi Igboho ati Kanu naa silẹ.”

Nigba to n sọrọ lori ọrọ ominira ti awọn kan n ja fun, Ladọja to tun jẹ Osi Olubadan tilẹ Ibadan, ṣalaye pe “ariwo ti awa Yoruba n pa lori ọrọ ominira yii ti pọ ju, awọn ara Oke-Ọya paapaa naa ti n mura silẹ de ominira, ṣugbọn eyi ti awa fi n pariwo lasan yii, awọn ti n ṣiṣẹ silẹ labẹnu lori bi wọn yóò ṣe máa ṣètò ara wọn nigba ti kaluku ba da duro tan, ki i ṣe pe wọn kan n pariwo bii tiwa.”

 

 

Leave a Reply