Faith Adebọla, Eko
Ere asadigbolura-ẹni ati akọlukọgba gidi lo waye lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde yii, pẹlu bawọn ero ọkọ ijọba BRT kan ṣe gbina lori irin n’Ikorodu, nipinlẹ Eko.
Ọgbẹni Ibrahim Farinloye, ọga agba ajọ ijọba apapọ to n ri si ọrọ pajawiri, ẹkun ti Guusu/Iwọ-Oorun fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ero marundinlaaadọta lo wa ninu ọkọ naa pẹlu dẹrẹba ọkọ ọhun, lasiko tiṣẹlẹ naa waye, nitosi ibudokọ Anthony.
O ni ko sẹni to padanu ẹmi rẹ ninu iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan diẹ fara pa nibi ti wọn ti n sa asala fun ẹmi wọn. O lawọn kan ti wọn gba oju ferese ọkọ naa bọ silẹ, tabi awọn ti gilaasi ọkọ naa ha lara ti lọọ gba itọju nileewosan.
Ilu Ikorodu ni wọn lọkọ gbọgbọrọ naa ti gbera, ibudokọ Tafawa Balewa, nisalẹ Eko, lọhun-un lo si n lọ ki wahala to fa ina naa too ṣẹlẹ si i.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣokunfa ina ojiji naa gan-an