Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ijọba Ekiti ti ṣeleri eto ilera to peye fawọn eeyan ipinlẹ naa pẹlu bi oriṣiiriṣii irinṣẹ ilera towo wọn to ọọdunrun miliọnu (300m) ṣe balẹ siluu Ado-Ekiti, iyẹn nileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ekiti (EKSUTH).
Awọn irinṣẹ naa ti ALAROYE gbọ pe awọn ajọ Global Fund fi ta Ekiti lọrẹ ni wọn yoo pin si ileewosan mejidinlaaadọta kaakiri ipinlẹ naa.
Nibi ifilọlẹ awọn irinṣẹ ọhun ni Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi to jẹ igbakeji gomina, to si ṣoju Gomina Kayọde Fayẹmi, ti sọ pe ijọba n wa gbogbo ọna lati gbe eto ilera larugẹ, ajọṣepọ pẹlu ijọba apapọ atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ si ti n so eso rere.
O waa rọ araalu lati lo anfaani awọn igbesẹ tuntun wọnyi tijọba ṣagbekalẹ lati din owo ti wọn n na lori eto ilera ku.
Ṣaaju ni Kọmiṣanna fero ilera, Dokita Oyebanji Filani, ti sọ pe asiko to daa lawọn irinṣẹ naa de, nitori ijọba ti bẹrẹ atunṣẹ awọn ileewosan kaakiri Ekiti, eyi yoo si ran awọn eeyan lọwọ lati ri iwosan to poju owo.
O waa dupẹ lọwọ awọn to n ṣeranwọ fun ijọba lori eto ilera bii Ọgbẹni Ibrahim Faria lati Global Fund, Mr Dozie Ezechukwu ati Tajudeen Ibrahim lati Country Coordinating Mechanism (CCM) pẹlu Dokita Olumide Elegbede ati Dokita Abiọdun Hassan lati Management Sciences for Health(MSH).