Ijọba Eko gbẹsẹ le ọkada bii aadoje, wọn ni wọn ṣẹ sofin irinna

Jide Alabi

Nitori pe wọn n rin lawọn ibi ti ijọba ti fofin de pe wọn ko gbọdọ de, awọn ọkada bii aadoje ni ijọba ipinlẹ Eko ti gbẹsẹ le nipinlẹ Eko lọjọ Aje, Mọnde, ọse yii. Ileeṣẹ to n ri si titẹle ofin imọtoto nipinlẹ Eko (Lagos State Sanitation Enforcement Agency), lo ko awọn ọkada ọhun. Bakan naa ni wọn mu awọn awakọ marun-un to wakọ lodi si ofin irinna.

Aarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde,  ni awọn ikọ bii ọgọrin ọhun, eyi ti ọga wọn, Shola Jẹjẹloye to jẹ ọga ọlọpaa dari, ya bo awọn ọlọkada to n gbero lawọn ibi ti ijọba sọ pe wọn ko gbọdọ ti maa ṣiṣẹ n’Iyana Ipaja.

Abule-Ẹgba ni wọn mori le nigba ti wọn kuro ni Iyana Ipaja, nibi ti awọn ọkọ ti n gba ọna ti ko yẹ ki wọn gba, ti awọn ọlọkada atawọn onimọto mi-in si n kọju si awọn ọkọ to n bọ, leyii ti wọn fi da sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ silẹ ni gbogbo agbegbe naa. Bi wọn ṣe n ri wọn ni wọn n fọwọ ofin mu wọn.

Jẹjẹloye ni lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn ti bẹrẹ eto ọhun, gbogbo asiko ọdun lawọn yoo maa jade lati mojuto bi awọn ọlọkada ṣe n ṣiṣẹ wọn lati ri i pe awọn ti wọn maa n fi ọkada jale lasiko ọdun ko raaye ṣịṣẹ buruku naa.

Bẹẹ lo sọ pe ki awọn ọlọkada ti ko ba ti ṣẹ sofin tabi ti wọn ko lọ si awọn ibi ti ijọba ba ni ki wọn ma lọ ma ṣe foya, nitori awọn ko ni i de ọdọ wọn. O fi kun un pe awọn ko wa lati da wahala silẹ tabi lati gba ounjẹ lẹnu ẹnikẹni, bi ko ṣe lati ri i pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ, ati pe awọn onimọto ati ọlọkada bọwọ fun ofin irinna.

Leave a Reply