Jọkẹ Amọri
Ijọba ipinlẹ Eko ti ni ileewe Dowen College, to wa ni Ikoyi, atawọn akẹkọọ marun-un ti wọn ko lori iṣẹlẹ naa ko mọ ohunkohun nipa iku ọmọ ọdun mejila to jẹ akẹkọọ ileewe naa, Sylvester Oromoni, to ku. Wọn ni awọn tẹle amọran ẹka eto idajọ lati ọdọ ọga agba ileeṣẹ to maa n gba ijọba nimọran nipinlẹ Eko, Arabinrin Adetutu Oshinusi.
Bakan naa ni wọn ni ko si ẹri to gbopọn lati fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ wọnyi wa ninu ẹgbẹ okunkun tabi ẹgbẹkẹgbẹ mi-in.
Siwaju si i, wọn ni nnkan kan naa ni abọ iwadii nipa iku to pa ọmọ naa ti wọn ṣe nipinlẹ Delta ati Eko, ti ko si ni i ṣe pẹlu ẹsun pe ẹnikẹni lo pa a.