Ijọba fẹẹ gba awọn ọdọ siṣẹ Amọtẹkun l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi iṣẹlẹ ijinigbe ṣe n waye lemọlemọ nipinlẹ Ọyọ, lẹnu lọọlọọ yii, Gomina Ṣeyi Makinde, ti bẹrẹ eto lati gba awọn eeyan to da pe, ti wọn si lalaafia sẹnu iṣẹ Amọtẹkun.

Makinde fidi eyi mulẹ ninu atẹjade ti oludari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ọgagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, fi sita, eyi to tẹ akọroyin wa lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ninu awọn eeyan ti wọn fẹẹ gba yii la ti ri awọn ọdẹ ibilẹ ti wọn yoo maa wọ inu igbo tọ awọn oniṣẹ ibi lọ.

“Ẹnikẹni to ba nifẹẹ si iṣẹ yii ni lati kan si ikanni igbanisiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, ki onitọhun si lo itakun ayelujara isalẹ yii lati forukọ silẹ:

www.jobportal.oyostate.gov.ng

Ikanni igbanisiṣẹ ti wa ni ṣiṣi silẹ bayii lati ọjọ Abamẹta, (Sátidé), ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, titi di ọgbọnjọ (30), oṣu yii, kan naa.

Amọ ṣa o, oluwaṣẹ gbọdọ ri i daju pe nọmba idanimọ wa lọwọ oke, lapa osi fọọmu rẹ. ‘AMOD’ ni yoo bẹrẹ nọnba naa.

“Awọn eeyan to lalaafia, tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) si aadọta (50) ọdun nìkan ni iṣẹ yii wa fun.

“Ẹ waa gbọ o, kikida awọn ọmọluabi eeyan nikan ni iṣẹ yii wa fun o, ko si fun ẹni to ba ti ṣẹwọn ri tabo to ti ni akọsilẹ iwa ọdaran ri.

“Ẹka aṣọgbo la fẹẹ gba awọn eeyan si. Nitori naa, gbogbo inu igbo ti awọn amookunṣika maa n fara pamọ lati ṣiṣẹ ibi ni ipinlẹ yii, ni gbogbo wọn yoo maa ṣọ kaakiri lati maa daabo bo ẹmi atí dukia awọn araalu, pẹlu ohun alumọọni ijọba to wa ninu aginju igbo gbogbo”.

Alákòóso ìkọ Amọtẹkun ṣalaye siwaju pe, “lẹyin ti awọn oluwaṣẹ yii ba ti kọ gbogbo ohun to ba yẹ sinu fọọmu wọn lori ẹrọ ayelujara tan, ti wọn si ti fi i ranṣẹ lori ẹrọ ayelujara nibẹ, wọn ni lati tẹ fọọmu naa jade.

“Lẹyin naa ni wọn yoo ṣeyẹwo ilera wọn nileewosan to jẹ tijọba, ki dokita to jẹ akọṣẹmọṣẹ si fọwọ si i.

Awọn adari ilu ati alaga ijọba ibilẹ oluwaṣẹ gbọdọ buwọ lu fọọmu rẹ laaye ti a pese silẹ fun olukuluku wọn. Gbogbo fọọmu ti oluwaṣẹ tẹ jade ni alakooso eto ibura nile-ẹjọ to kunju oṣunwọn gbọdọ lu lontẹ. Lẹyin naa ni wọn yoo ko gbogbo fọọmu ti wọn ba ti fọwọ si gẹgẹ bo ṣe yẹ lọ si ibi ti a maa kede fun wọn nigba ti asiko ba to”.

Amọ ṣa, wọn ni anfani iṣẹ yii kò sí fun ẹnikẹni to ba ti ṣiṣẹ pẹlu Amọtẹkun ri, ṣugbọn to jẹ pe niṣe ni wọn le e danu, bi iru ẹni bẹẹ ba fifẹ han si iṣẹ yii, oluwarẹ kan n fasiko ara ẹ ṣofo lasan ni, wọn ko ni i gba a.

Leave a Reply