Ijọba gbọdọ tete fopin si wahala Yoruba ati Hausa ni Ṣáṣá ko too dogun o- Baalẹ Ṣaṣa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Baálẹ̀ agbegbe Ṣáṣá, niluu Ibadan, Oloye Amusa Akinade, ti rawọ ẹbẹ sí àwọn ìjọba lẹ́lẹ́kajẹ̀ka lati wa gbogbo ọna lati fopin sí aawọ to waye laarin Yorùbá ati Hausa lagbegbe naa ki rogbodiyan ọhun ma baa yọrí sí ogun abẹle.

Lasiko abẹwo ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ati Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu pẹlu CP Ngozi Onadeko, ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, ṣe sí Ṣáṣá lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, lo sọrọ náà.

Olóyè Akinade, ẹni tó fi aidunnu ẹ̀ hàn lori làásìgbò ọhún, sọ pé “Kayeefi lo jẹ fún mi pé àwọn tó pa ọkunrin soobata naa ni wọn tun n dana sun ile ati dukia awọn eeyan kaakiri.”

Nigba to n ṣalaye bi rogbodiyan ọhun ṣe waye, Baálẹ̀ Ṣáṣá royin pe “Ija to pa Hausa kan ati aláboyún kan pọ ló da wahala yii silẹ. Soobata to n gbiyanju lati ba wọn parí ẹ̀ l’Ausa yẹn lù ni nnkan ti ìyẹn sí gbẹmi-in mi lọjọ keji.

 

“Awọn to paayan yii naa ni wọn tun wa n dana sunle káàkiri. Wọn tun wa n fi wa ṣe yẹyẹ pe ti Ṣaṣa kò ba ṣee gbe mọ, awọn aa si gba ilẹ ibomi-in lọ.

“O ya wa lẹnu pe ijọba ko tete gbe igbesẹ to yẹ ki wọn gbe lati tete dènà wahala yii. Wọn ko sọrọ sibi tọrọ wa rara.  Ẹ tiẹ gbọ na. Ṣe ijọba n bẹru awọn èèyàn yìí ni?

A kò sọ pé kí àwọn èèyàn máa já. A ti sọ fún àwọn èèyàn wa (Yorùbá) lati gba alaafia laaye. Ṣugbọn a fẹ ki awọn Hausa náa sinmi a n paayan, a n dana sunle kiri.”

Ninu ọrọ tiẹ, ọkan ninu awọn to fara gbá nínú aáwọ̀ yii, Abilekọ Oṣuọale Mosurat, ẹni to n ta ounjẹ ninu ọja Ṣáṣá, sọ pé “Nnkan ko buru to bayii ri lati ọdun mẹjọ ti mo ti n taja níbí. Niṣe lawọn Hausa dana sun ṣọọbu mi. Awọn ohun eelo ounjẹ to wa nibẹ lasan ju ẹgbẹrun lọna igba (₦200,000) naira lọ.”

Gomina Makinde ati Arakunrin Akeredolu fi aidunnu wọn hàn sí làásìgbò naa. Wọn sì rọ àwọn ará Ṣáṣá, Yoruba, ati Hausa, lati gba alaafia laaye nitori idagbasoke kankan ko le waye láwùjọ ti ko ba ti sí ibalẹ ọkan fawọn araalu.

Bakan naa ni Gomina Makinde fi awọn to padanu dukia wọn lọkan balẹ pe ijọba yóò wá nnkan ṣe lori ẹ̀ lati dùn wọn ninu.

Leave a Reply